Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #27 Translated in Yoruba

وَأُدْخِلَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا بِإِذْنِ رَبِّهِمْ ۖ تَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَامٌ
Won si maa mu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re pelu ase Oluwa won. Ikini won ninu re ni ‘alaafia’
أَلَمْ تَرَ كَيْفَ ضَرَبَ اللَّهُ مَثَلًا كَلِمَةً طَيِّبَةً كَشَجَرَةٍ طَيِّبَةٍ أَصْلُهَا ثَابِتٌ وَفَرْعُهَا فِي السَّمَاءِ
Se o o ri bi Allahu ti sakawe oro daadaa pelu igi daadaa, ti gbongbo re fidi mule sinsin, ti eka re si wa ninu sanmo
تُؤْتِي أُكُلَهَا كُلَّ حِينٍ بِإِذْنِ رَبِّهَا ۗ وَيَضْرِبُ اللَّهُ الْأَمْثَالَ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
to si n so eso (jije) re ni gbogbo igba pelu iyonda Oluwa re? Allahu n fun awon eniyan ni awon akawe nitori ki won le lo iranti
وَمَثَلُ كَلِمَةٍ خَبِيثَةٍ كَشَجَرَةٍ خَبِيثَةٍ اجْتُثَّتْ مِنْ فَوْقِ الْأَرْضِ مَا لَهَا مِنْ قَرَارٍ
Akawe oro ti ko dara si da bi igi ti ko dara, ti won fa tu lati oke lori ile, ti ko si ni aye kan lori ile
يُثَبِّتُ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا بِالْقَوْلِ الثَّابِتِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۖ وَيُضِلُّ اللَّهُ الظَّالِمِينَ ۚ وَيَفْعَلُ اللَّهُ مَا يَشَاءُ
Allahu yoo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo rinle pelu oro t’o rinle ninu isemi aye ati ni Ojo Ikeyin. O si maa si awon alabosi lona. Ati pe Allahu n se ohun ti O ba fe

Choose other languages: