Quran Apps in many lanuages:

Surah Hud Ayahs #58 Translated in Yoruba

إِنْ نَقُولُ إِلَّا اعْتَرَاكَ بَعْضُ آلِهَتِنَا بِسُوءٍ ۗ قَالَ إِنِّي أُشْهِدُ اللَّهَ وَاشْهَدُوا أَنِّي بَرِيءٌ مِمَّا تُشْرِكُونَ
nkan ti a n so fun o ni pe awon kan ninu awon orisa wa ti fi inira kan o (l’o fi n so isokuso nipa won)." O so pe: "Dajudaju emi n fi Allahu se Elerii ati pe ki eyin naa jerii pe dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n fi sebo
مِنْ دُونِهِ ۖ فَكِيدُونِي جَمِيعًا ثُمَّ لَا تُنْظِرُونِ
dipo jijosin fun Allahu. Nitori naa, e parapo dete si mi. Leyin naa, ki e ma se lo mi lara
إِنِّي تَوَكَّلْتُ عَلَى اللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمْ ۚ مَا مِنْ دَابَّةٍ إِلَّا هُوَ آخِذٌ بِنَاصِيَتِهَا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Dajudaju emi gbarale Allahu, Oluwa mi ati Oluwa yin. Ko si eda kan afi ki (o je pe) Oun l’O maa fi aaso ori re mu un. Dajudaju Oluwa mi wa lori ona taara
فَإِنْ تَوَلَّوْا فَقَدْ أَبْلَغْتُكُمْ مَا أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَيْكُمْ ۚ وَيَسْتَخْلِفُ رَبِّي قَوْمًا غَيْرَكُمْ وَلَا تَضُرُّونَهُ شَيْئًا ۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ حَفِيظٌ
Nitori naa, ti e ba peyin da (nibi ododo), mo kuku ti fi ohun ti Won fi ran mi nise jise fun yin, Oluwa mi yo si fi ijo kan t’o maa yato si eyin ropo yin. E o si le ko inira kan kan ba A. Dajudaju Oluwa mi ni Oluso lori gbogbo nnkan
وَلَمَّا جَاءَ أَمْرُنَا نَجَّيْنَا هُودًا وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ بِرَحْمَةٍ مِنَّا وَنَجَّيْنَاهُمْ مِنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ
Nigba ti ase Wa de, A gba (Anabi) Hud ati awon t’o gbagbo pelu re la pelu ike lati odo Wa; A gba won la ninu iya t’o nipon

Choose other languages: