Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #10 Translated in Yoruba

وَكَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ كَفَرُوا أَنَّهُمْ أَصْحَابُ النَّارِ
Ati pe bayen ni oro Oluwa re se ko lori awon t’o sai gbagbo pe: "Dajudaju awon ni ero inu Ina
الَّذِينَ يَحْمِلُونَ الْعَرْشَ وَمَنْ حَوْلَهُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيُؤْمِنُونَ بِهِ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا وَسِعْتَ كُلَّ شَيْءٍ رَحْمَةً وَعِلْمًا فَاغْفِرْ لِلَّذِينَ تَابُوا وَاتَّبَعُوا سَبِيلَكَ وَقِهِمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ
Awon t’o gbe Ite-ola naa ru ati awon t’o wa ni ayika re, won n se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won gba Allahu gbo. Won si n toro aforijin fun awon t’o gbagbo ni ododo (bayii pe): "Oluwa wa, ike ati imo (Re) gbooro ju gbogbo nnkan lo, nitori naa, saforijin fun awon t’o ronu piwada, ti won si tele oju-ona Re. Ki O si so won ninu iya ina Jehim
رَبَّنَا وَأَدْخِلْهُمْ جَنَّاتِ عَدْنٍ الَّتِي وَعَدْتَهُمْ وَمَنْ صَلَحَ مِنْ آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۚ إِنَّكَ أَنْتَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Oluwa wa, fi won sinu awon Ogba Idera ti O se ni adehun fun awon ati eni t’o se ise rere ninu awon baba won, awon aya won ati awon aromodomo won. Dajudaju Iwo ni Alagbara, Ologbon
وَقِهِمُ السَّيِّئَاتِ ۚ وَمَنْ تَقِ السَّيِّئَاتِ يَوْمَئِذٍ فَقَدْ رَحِمْتَهُ ۚ وَذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
So won ninu awon aburu. Enikeni ti O ba so nibi awon aburu (iya) ni ojo yen, dajudaju O ti ke e. Iyen si ni erenje nla
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا يُنَادَوْنَ لَمَقْتُ اللَّهِ أَكْبَرُ مِنْ مَقْتِكُمْ أَنْفُسَكُمْ إِذْ تُدْعَوْنَ إِلَى الْإِيمَانِ فَتَكْفُرُونَ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, won yoo pe won (lati so fun won ninu Ina pe): " Dajudaju ibinu ti Allahu tobi ju ibinu ti e n bi sira yin (ninu Ina, sebi) nigba ti won n pe yin sibi igbagbo ododo, nse ni e n sai gbagbo

Choose other languages: