Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #70 Translated in Yoruba

قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَمَّا جَاءَنِيَ الْبَيِّنَاتُ مِنْ رَبِّي وَأُمِرْتُ أَنْ أُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ
So pe: "Dajudaju Won ko fun mi pe ki ng josin fun awon ti e n pe leyin Allahu, nigba ti awon eri t’o yanju ti de ba mi lati odo Oluwa mi, ti won si pa mi ni ase pe ki ng juwo juse sile (ki ng je musulumi) fun Oluwa gbogbo eda
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ تُرَابٍ ثُمَّ مِنْ نُطْفَةٍ ثُمَّ مِنْ عَلَقَةٍ ثُمَّ يُخْرِجُكُمْ طِفْلًا ثُمَّ لِتَبْلُغُوا أَشُدَّكُمْ ثُمَّ لِتَكُونُوا شُيُوخًا ۚ وَمِنْكُمْ مَنْ يُتَوَفَّىٰ مِنْ قَبْلُ ۖ وَلِتَبْلُغُوا أَجَلًا مُسَمًّى وَلَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Oun ni Eni ti O seda yin lati inu erupe, leyin naa lati inu ato, leyin naa lati inu eje didi, leyin naa O mu yin jade ni oponlo. Leyin naa, (O da yin si) nitori ki e le sanngun dopin agbara yin. Leyin naa (O tun da yin si) nitori ki e le di agbalagba. O wa ninu yin eni ti A oo ti gba emi re siwaju (ipo agba). Ati pe (O da yin si) nitori ki e le dagba de gbedeke akoko kan ati nitori ki e le se laakaye
هُوَ الَّذِي يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ
Oun ni Eni ti n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: "Je bee." O si maa je bee
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ يُجَادِلُونَ فِي آيَاتِ اللَّهِ أَنَّىٰ يُصْرَفُونَ
Se o o ri awon ti n sariyanjiyan nipa awon ayah Allahu bi won se n seri won kuro nibi ododo
الَّذِينَ كَذَّبُوا بِالْكِتَابِ وَبِمَا أَرْسَلْنَا بِهِ رُسُلَنَا ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ
Awon t’o pe Tira naa ati ohun ti A fi ran awon Ojise Wa niro, laipe won maa mo

Choose other languages: