Quran Apps in many lanuages:

Surah Ghafir Ayahs #66 Translated in Yoruba

ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Eledaa gbogbo nnkan. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
كَذَٰلِكَ يُؤْفَكُ الَّذِينَ كَانُوا بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ
Bayen naa ni won se n se awon t’o n tako awon ayah Allahu lori kuro nibi ododo (siwaju tiwon)
اللَّهُ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ قَرَارًا وَالسَّمَاءَ بِنَاءً وَصَوَّرَكُمْ فَأَحْسَنَ صُوَرَكُمْ وَرَزَقَكُمْ مِنَ الطَّيِّبَاتِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ ۖ فَتَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Allahu ni Eni ti O se ile fun yin ni ibugbe. O mo sanmo (le yin lori). O ya aworan yin. O si ya aworan yin daradara. O pese arisiki fun yin ninu awon nnkan daadaa. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, mimo ni fun Allahu, Oluwa gbogbo eda
هُوَ الْحَيُّ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ ۗ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ
Oun ni Alaaye. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, e pe E ni ti olusafomo-esin fun Un. Gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda
قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لَمَّا جَاءَنِيَ الْبَيِّنَاتُ مِنْ رَبِّي وَأُمِرْتُ أَنْ أُسْلِمَ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ
So pe: "Dajudaju Won ko fun mi pe ki ng josin fun awon ti e n pe leyin Allahu, nigba ti awon eri t’o yanju ti de ba mi lati odo Oluwa mi, ti won si pa mi ni ase pe ki ng juwo juse sile (ki ng je musulumi) fun Oluwa gbogbo eda

Choose other languages: