Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #34 Translated in Yoruba

لِيُوَفِّيَهُمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدَهُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ غَفُورٌ شَكُورٌ
(Won n se bee) nitori ki Allahu le san won ni esan rere won ati nitori ki O le se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Dajudaju Oun ni Alaforijin, Olope
وَالَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ مِنَ الْكِتَابِ هُوَ الْحَقُّ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِعِبَادِهِ لَخَبِيرٌ بَصِيرٌ
Ohun ti A fi ranse si o ninu Tira, ohun ni ododo ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju re. Dajudaju Allahu ni Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re
ثُمَّ أَوْرَثْنَا الْكِتَابَ الَّذِينَ اصْطَفَيْنَا مِنْ عِبَادِنَا ۖ فَمِنْهُمْ ظَالِمٌ لِنَفْسِهِ وَمِنْهُمْ مُقْتَصِدٌ وَمِنْهُمْ سَابِقٌ بِالْخَيْرَاتِ بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَضْلُ الْكَبِيرُ
Leyin naa, A jogun tira (al-Ƙur’an) fun awon ti A sa lesa ninu awon erusin Wa. Nitori naa, alabosi t’o n bo emi ara re si wa ninu won. Oluse-deede wa ninu won. Olugbawaju nibi awon ise rere tun wa ninu won pelu iyonda Allahu. Iyen si ni oore ajulo t’o tobi
جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا يُحَلَّوْنَ فِيهَا مِنْ أَسَاوِرَ مِنْ ذَهَبٍ وَلُؤْلُؤًا ۖ وَلِبَاسُهُمْ فِيهَا حَرِيرٌ
Awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo inu re. Awon kerewu wura ati okuta olowo iyebiye ni A oo maa fi se oso fun won ninu re. Ati pe aso alaari ni aso won ninu re
وَقَالُوا الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَذْهَبَ عَنَّا الْحَزَنَ ۖ إِنَّ رَبَّنَا لَغَفُورٌ شَكُورٌ
Won yoo so pe: “Gbogbo ope n je ti Allahu, Eni ti O mu ibanuje kuro fun wa. Dajudaju Oluwa wa ni Alaforijin, Olope

Choose other languages: