Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #28 Translated in Yoruba

إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ بِالْحَقِّ بَشِيرًا وَنَذِيرًا ۚ وَإِنْ مِنْ أُمَّةٍ إِلَّا خَلَا فِيهَا نَذِيرٌ
Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo. Ko si ijo kan (siwaju re) afi ki olukilo ti re koja laaarin won
وَإِنْ يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ وَبِالزُّبُرِ وَبِالْكِتَابِ الْمُنِيرِ
Ti won ba si n pe o ni opuro, awon t’o siwaju won naa kuku pe (oro Allahu) niro (nigba ti) awon Ojise won wa ba won pelu awon eri t’o yanju, awon ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin
ثُمَّ أَخَذْتُ الَّذِينَ كَفَرُوا ۖ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Leyin naa, Mo gba awon t’o sai gbagbo mu. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ ثَمَرَاتٍ مُخْتَلِفًا أَلْوَانُهَا ۚ وَمِنَ الْجِبَالِ جُدَدٌ بِيضٌ وَحُمْرٌ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهَا وَغَرَابِيبُ سُودٌ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo? A si fi mu awon eso ti awo re yato sira won jade. Ati pe awon oju ona funfun ati pupa ti awo re yato sira won pelu alawo dudu kirikiri wa ninu awon apata
وَمِنَ النَّاسِ وَالدَّوَابِّ وَالْأَنْعَامِ مُخْتَلِفٌ أَلْوَانُهُ كَذَٰلِكَ ۗ إِنَّمَا يَخْشَى اللَّهَ مِنْ عِبَادِهِ الْعُلَمَاءُ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ غَفُورٌ
Ati pe o wa ninu awon eniyan, awon nnkan elemii ati awon eran-osin ti awo won yato sira won, gege bi (awo eso ati apata) wonyen (se yato sira won). Awon t’o n paya Allahu ninu awon erusin Re ni awon onimo (ti won mo pe), dajudaju Allahu ni Alagbara, Alaforijin

Choose other languages: