Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zamar Ayahs #23 Translated in Yoruba

أَفَمَنْ حَقَّ عَلَيْهِ كَلِمَةُ الْعَذَابِ أَفَأَنْتَ تُنْقِذُ مَنْ فِي النَّارِ
Se eni ti oro iya Ina ti kole lori (nipa aigbagbo re, se ko nii wona ni?) Se iwo l’o maa la eni t’o wa ninu Ina (nipase aigbagbo re) ni
لَٰكِنِ الَّذِينَ اتَّقَوْا رَبَّهُمْ لَهُمْ غُرَفٌ مِنْ فَوْقِهَا غُرَفٌ مَبْنِيَّةٌ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ الْمِيعَادَ
Sugbon awon t’o beru Oluwa won, tiwon ni awon ile giga, ti awon ile giga tun wa loke re, awon odo yo si maa san ni isale re. Adehun Allahu ni (eyi). Allahu ko si nii ye adehun naa
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَسَلَكَهُ يَنَابِيعَ فِي الْأَرْضِ ثُمَّ يُخْرِجُ بِهِ زَرْعًا مُخْتَلِفًا أَلْوَانُهُ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَاهُ مُصْفَرًّا ثُمَّ يَجْعَلُهُ حُطَامًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكْرَىٰ لِأُولِي الْأَلْبَابِ
Se o o ri i pe dajudaju Allahu l’O so omi kale lati sanmo, O si mu omi naa bo sinu awon opopona odo ninu ile, leyin naa, O n fi mu irugbin ti awo won yato sira won jade, leyin naa, (irugbin naa) yoo gbe, o si maa ri i ni pipon, leyin naa, O maa so o di rirun? Dajudaju iranti wa ninu iyen fun awon onilaakaye
أَفَمَنْ شَرَحَ اللَّهُ صَدْرَهُ لِلْإِسْلَامِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٍ مِنْ رَبِّهِ ۚ فَوَيْلٌ لِلْقَاسِيَةِ قُلُوبُهُمْ مِنْ ذِكْرِ اللَّهِ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُبِينٍ
Nje eni ti Allahu gba okan re laaye fun esin ’Islam, ti o si wa ninu imole lati odo Oluwa re (da bi alaigbagbo bi)? Egbe ni fun awon ti okan won le si iranti Allahu. Awon wonyen wa ninu isina ponnbele
اللَّهُ نَزَّلَ أَحْسَنَ الْحَدِيثِ كِتَابًا مُتَشَابِهًا مَثَانِيَ تَقْشَعِرُّ مِنْهُ جُلُودُ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمْ وَقُلُوبُهُمْ إِلَىٰ ذِكْرِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُدَى اللَّهِ يَهْدِي بِهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ هَادٍ
Allahu l’O so oro t’o dara julo kale, (o je) Tira, ti (awon oro inu re) jora won ni oro asotunso, ti awo ara awon t’o n paya Oluwa won yo si maa wariri nitori re. Leyin naa, awo ara won ati okan won yoo maa ro nibi iranti Allahu. Iyen ni imona Allahu. O si n fi se imona fun eni ti O ba fe. Eni ti Allahu ba si lona, ko si nii si afinimona kan fun un

Choose other languages: