Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #7 Translated in Yoruba

9:3
وَأَذَانٌ مِنَ اللَّهِ وَرَسُولِهِ إِلَى النَّاسِ يَوْمَ الْحَجِّ الْأَكْبَرِ أَنَّ اللَّهَ بَرِيءٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ۙ وَرَسُولُهُ ۚ فَإِنْ تُبْتُمْ فَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ ۖ وَإِنْ تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ غَيْرُ مُعْجِزِي اللَّهِ ۗ وَبَشِّرِ الَّذِينَ كَفَرُوا بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Ikede kan lati odo Allahu ati Ojise Re si awon eniyan ni ojo Hajj Nla ni pe, “Dajudaju Allahu yowoyose (ninu oro) awon osebo. Ojise Re naa (yowoyose). Ti e ba ronu piwada, o si loore julo fun yin. Ti e ba gbunri, e mo pe dajudaju e o le moribo ninu (iya) Allahu.” Ki o si fun awon t’o sai gbagbo ni iro iya eleta-elero
9:4
إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ مِنَ الْمُشْرِكِينَ ثُمَّ لَمْ يَنْقُصُوكُمْ شَيْئًا وَلَمْ يُظَاهِرُوا عَلَيْكُمْ أَحَدًا فَأَتِمُّوا إِلَيْهِمْ عَهْدَهُمْ إِلَىٰ مُدَّتِهِمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Ayafi awon ti e ba se adehun ninu awon osebo, leyin naa, ti won ko si fi ona kan kan ye adehun yin, ti won ko si satileyin fun eni kan kan le yin lori. Nitori naa, e pe adehun won fun won titi di asiko won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)
9:5
فَإِذَا انْسَلَخَ الْأَشْهُرُ الْحُرُمُ فَاقْتُلُوا الْمُشْرِكِينَ حَيْثُ وَجَدْتُمُوهُمْ وَخُذُوهُمْ وَاحْصُرُوهُمْ وَاقْعُدُوا لَهُمْ كُلَّ مَرْصَدٍ ۚ فَإِنْ تَابُوا وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَآتَوُا الزَّكَاةَ فَخَلُّوا سَبِيلَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Nitori naa, nigba ti awon osu owo ba lo tan , e pa awon osebo nibikibi ti e ba ti ba won. E mu won, e sede mo won, ki e si ba de won ni gbogbo ibuba. Ti won ba si ronu piwada, ti won n kirun, ti won si n yo Zakah, e yago fun won loju ona. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
9:6
وَإِنْ أَحَدٌ مِنَ الْمُشْرِكِينَ اسْتَجَارَكَ فَأَجِرْهُ حَتَّىٰ يَسْمَعَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ أَبْلِغْهُ مَأْمَنَهُ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْلَمُونَ
Ti eni kan ninu awon osebo ba wa eto aabo wa sodo re, s’eto aabo fun un titi o fi maa gbo oro Allahu. Leyin naa, mu u de aye ifokanbale re. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko nimo
9:7
كَيْفَ يَكُونُ لِلْمُشْرِكِينَ عَهْدٌ عِنْدَ اللَّهِ وَعِنْدَ رَسُولِهِ إِلَّا الَّذِينَ عَاهَدْتُمْ عِنْدَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ فَمَا اسْتَقَامُوا لَكُمْ فَاسْتَقِيمُوا لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَّقِينَ
Bawo ni adehun kan yoo se wa fun awon osebo lodo Allahu ati lodo Ojise Re yato si awon ti e ba se adehun nitosi Mosalasi Haram? Nitori naa, ti won ba duro deede pelu yin, e duro deede pelu won. Dajudaju Allahu nifee awon oluberu (Re)

Choose other languages: