Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Sajda Ayahs #22 Translated in Yoruba

أَفَمَنْ كَانَ مُؤْمِنًا كَمَنْ كَانَ فَاسِقًا ۚ لَا يَسْتَوُونَ
Nje eni t’o je onigbagbo ododo da bi eni t’o je obileje bi? Won ko dogba
أَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَلَهُمْ جَنَّاتُ الْمَأْوَىٰ نُزُلًا بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, awon ibugbe (ninu) Ogba Idera n be fun won. (O je) ohun ti A pese sile (de won) nitori ohun ti won n se nise (rere)
وَأَمَّا الَّذِينَ فَسَقُوا فَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۖ كُلَّمَا أَرَادُوا أَنْ يَخْرُجُوا مِنْهَا أُعِيدُوا فِيهَا وَقِيلَ لَهُمْ ذُوقُوا عَذَابَ النَّارِ الَّذِي كُنْتُمْ بِهِ تُكَذِّبُونَ
Ni ti awon t’o baleje, Ina ni ibugbe won. Igbakigba ti won ba fe jade kuro ninu re, A o si maa da won pada sinu re. A si maa so fun won pe: “E to iya Ina ti e n pe niro wo.”
وَلَنُذِيقَنَّهُمْ مِنَ الْعَذَابِ الْأَدْنَىٰ دُونَ الْعَذَابِ الْأَكْبَرِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Dajudaju A maa fun won to wo ninu iya t’o kere julo (nile aye) yato si iya t’o tobi julo (lorun) nitori ki won le seri pada (sibi ododo siwaju iku won)
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ ذُكِّرَ بِآيَاتِ رَبِّهِ ثُمَّ أَعْرَضَ عَنْهَا ۚ إِنَّا مِنَ الْمُجْرِمِينَ مُنْتَقِمُونَ
Ati pe ta l’o se abosi t’o tayo eni ti won fi awon ayah Wa se isiti fun, leyin naa, ti o gbunri kuro nibe? Dajudaju Awa maa gbesan lara awon elese

Choose other languages: