Quran Apps in many lanuages:

Surah As-Sajda Ayahs #15 Translated in Yoruba

قُلْ يَتَوَفَّاكُمْ مَلَكُ الْمَوْتِ الَّذِي وُكِّلَ بِكُمْ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ
So pe: “Molaika iku eyi ti A fi ti yin maa gba emi yin. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won maa da yin pada si.” gege bi O se je Eledaa ohun gbogbo. Ko si eda kan ti o maa to isemi wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Ko si si eda kan ti o maa to iku wo afi pelu iyonda Allahu (subhanahu wa ta’ala). Nipa eyi Allahu l’O n fi ase Re gba emi kuro lara eda Re ni akoko ti O ti ko mo on ninu kadara. Iyen ni o jeyo ninu surah az-Zumor; 39:42. Bakan naa
وَلَوْ تَرَىٰ إِذِ الْمُجْرِمُونَ نَاكِسُو رُءُوسِهِمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ رَبَّنَا أَبْصَرْنَا وَسَمِعْنَا فَارْجِعْنَا نَعْمَلْ صَالِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ
(Iwo iba ri eemo) ti o ba je pe o ri awon elese nigba ti won ba sori ko ni odo Oluwa won, (won si maa wi pe): “Oluwa wa, a ti riran, a si ti gboran (bayii), nitori naa, da wa pada (si ile aye) nitori ki a le lo se ise rere; dajudaju awa ni alamodaju.”
وَلَوْ شِئْنَا لَآتَيْنَا كُلَّ نَفْسٍ هُدَاهَا وَلَٰكِنْ حَقَّ الْقَوْلُ مِنِّي لَأَمْلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ الْجِنَّةِ وَالنَّاسِ أَجْمَعِينَ
Ti o ba je pe A ba fe ni, dajudaju A iba fun gbogbo emi kookan ni imona re, sugbon oro naa ti se lati odo Mi (bayii pe): “Dajudaju Mo maa mu ninu awon alujannu ati eniyan ni apapo kun inu ina Jahanamo.”
فَذُوقُوا بِمَا نَسِيتُمْ لِقَاءَ يَوْمِكُمْ هَٰذَا إِنَّا نَسِينَاكُمْ ۖ وَذُوقُوا عَذَابَ الْخُلْدِ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Nitori naa, e to iya wo nitori pe e ti gbagbe ipade ojo yin (oni) yii. Dajudaju Awa naa yoo gbagbe yin sinu Ina. E to iya gbere wo nitori ohun ti e n se nise
إِنَّمَا يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا الَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا بِهَا خَرُّوا سُجَّدًا وَسَبَّحُوا بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَهُمْ لَا يَسْتَكْبِرُونَ ۩
Awon t’o gbagbo ninu awon ayah Wa ni awon ti o je pe nigba ti won ba fi se isiti fun won, won yoo doju bole ni oluforikanle, won yo si se afomo pelu idupe fun Oluwa won. Won ko si nii segberaga

Choose other languages: