Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #36 Translated in Yoruba

مِنَ الَّذِينَ فَرَّقُوا دِينَهُمْ وَكَانُوا شِيَعًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ
(E ma se wa) ninu awon t’o da esin won si kelekele, ti won si di ijo-ijo. Ijo kookan si n yo si ohun ti o wa lodo won
وَإِذَا مَسَّ النَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا رَبَّهُمْ مُنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا أَذَاقَهُمْ مِنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِنْهُمْ بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ
Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, won yoo pe Oluwa won, ti won yoo maa seri pada sodo Re. Leyin naa, nigba ti (Allahu) ba fun won ni ike kan to wo lati odo Re, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa sebo si Oluwa won
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ
nitori ki won le sai moore si ohun ti (Allahu) fun won. E maa jaye lo. Nitori naa, laipe e maa mo
أَمْ أَنْزَلْنَا عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُوا بِهِ يُشْرِكُونَ
Tabi A so eri kan kale fun won, t’o n soro nipa nnkan ti won n so di akegbe Re
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا بِهَا ۖ وَإِنْ تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ
Nigba ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo, won yoo dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan won nipa ohun ti owo won ti siwaju, nigba naa ni won yoo soreti nu

Choose other languages: