Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #23 Translated in Yoruba

أَفَمَنْ يَعْلَمُ أَنَّمَا أُنْزِلَ إِلَيْكَ مِنْ رَبِّكَ الْحَقُّ كَمَنْ هُوَ أَعْمَىٰ ۚ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُولُو الْأَلْبَابِ
Nje eni ti o mo pe ododo kuku ni nnkan ti won sokale fun o lati odo Oluwa re da bi eni ti o foju (nipa re)? Awon onilaakaye l’o n lo iranti
الَّذِينَ يُوفُونَ بِعَهْدِ اللَّهِ وَلَا يَنْقُضُونَ الْمِيثَاقَ
(Awon ni) awon t’o n mu adehun Allahu se. Ati pe won ki i tu adehun
وَالَّذِينَ يَصِلُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوءَ الْحِسَابِ
(Awon ni) awon t’o n da ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo po. Won n paya Oluwa won. Won si n paya aburu isiro-ise
وَالَّذِينَ صَبَرُوا ابْتِغَاءَ وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَنْفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عُقْبَى الدَّارِ
(Awon ni) awon t’o se suuru lati fi wa Oju rere Oluwa won. Won n kirun. Won n na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba. Won si n fi rere ti aburu lo. Awon wonyen ni atubotan Ile rere n be fun
جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا وَمَنْ صَلَحَ مِنْ آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ يَدْخُلُونَ عَلَيْهِمْ مِنْ كُلِّ بَابٍ
Inu awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo, (awon) ati eni t’o ba se rere ninu awon baba won, awon iyawo won ati awon aromodomo won. Awon molaika yo si maa wole to won lati enu ona kookan

Choose other languages: