Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #24 Translated in Yoruba

وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ وَأَنَّ اللَّهَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ
Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni (Allahu iba tete fiya je yin ni). Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Asake-orun
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ وَمَنْ يَتَّبِعْ خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ فَإِنَّهُ يَأْمُرُ بِالْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ ۚ وَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ مَا زَكَىٰ مِنْكُمْ مِنْ أَحَدٍ أَبَدًا وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يُزَكِّي مَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se tele awon oju-ese Esu. Enikeni ti o ba si tele awon oju-ese Esu, dajudaju (Esu) yoo pase iwa ibaje ati aburu (fun un). Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati ike Re lori yin ni, eni kan iba ti mo ninu yin laelae. Sugbon Allahu n safomo eni ti O ba fe. Allahu si ni Olugbo, Onimo
وَلَا يَأْتَلِ أُولُو الْفَضْلِ مِنْكُمْ وَالسَّعَةِ أَنْ يُؤْتُوا أُولِي الْقُرْبَىٰ وَالْمَسَاكِينَ وَالْمُهَاجِرِينَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۖ وَلْيَعْفُوا وَلْيَصْفَحُوا ۗ أَلَا تُحِبُّونَ أَنْ يَغْفِرَ اللَّهُ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ki awon t’o ni ola ati igbalaaye ninu yin ma se bura pe awon ko nii se daadaa si awon ibatan, awon mekunnu ati awon t’o gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu. Ki won saforijin, ki won si samojukuro. Se e o fe ki Allahu forijin yin ni? Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
إِنَّ الَّذِينَ يَرْمُونَ الْمُحْصَنَاتِ الْغَافِلَاتِ الْمُؤْمِنَاتِ لُعِنُوا فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَلَهُمْ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Dajudaju awon t’o n paro sina mo awon omoluabi l’obinrin, awon ti sina ko si lori okan won, awon onigbagbo ododo lobinrin, A ti sebi le won ni aye ati ni orun. Iya nla si wa fun won
يَوْمَ تَشْهَدُ عَلَيْهِمْ أَلْسِنَتُهُمْ وَأَيْدِيهِمْ وَأَرْجُلُهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ni ojo ti awon ahon won, owo won ati ese won yoo maa jerii tako won nipa ohun ti won n se nise

Choose other languages: