Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #174 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمُ الرَّسُولُ بِالْحَقِّ مِنْ رَبِّكُمْ فَآمِنُوا خَيْرًا لَكُمْ ۚ وَإِنْ تَكْفُرُوا فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Eyin eniyan, dajudaju Ojise naa ti de ba yin pelu ododo lati odo Oluwa yin. Nitori naa, ki e gba a gbo l’o dara julo fun yin. Ti e ba si sai gbagbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Allahu si n je Onimo, Ologbon
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَا تَغْلُوا فِي دِينِكُمْ وَلَا تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ إِلَّا الْحَقَّ ۚ إِنَّمَا الْمَسِيحُ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ رَسُولُ اللَّهِ وَكَلِمَتُهُ أَلْقَاهَا إِلَىٰ مَرْيَمَ وَرُوحٌ مِنْهُ ۖ فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ ۖ وَلَا تَقُولُوا ثَلَاثَةٌ ۚ انْتَهُوا خَيْرًا لَكُمْ ۚ إِنَّمَا اللَّهُ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ سُبْحَانَهُ أَنْ يَكُونَ لَهُ وَلَدٌ ۘ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَكِيلًا
Eyin ahlul-kitab, e ma se tayo enu-ala ninu esin yin, ki e si ma so ohun kan nipa Allahu afi ododo. Ojise Allahu ni Mosih ‘Isa omo Moryam. Oro Re (kun fayakun) ti O so ranse si Moryam l’O si fi seda re. Emi kan (ti Allahu seda) lati odo Re si ni (Mosih ‘Isa omo Moryam). Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati awon Ojise Re. E ye so meta (lokan) mo. Ki e jawo nibe lo je oore fun yin. Allahu nikan ni Olohun, Okan soso (ti ijosin to si). O mo tayo ki O ni omo. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si to ni Alamojuuto
لَنْ يَسْتَنْكِفَ الْمَسِيحُ أَنْ يَكُونَ عَبْدًا لِلَّهِ وَلَا الْمَلَائِكَةُ الْمُقَرَّبُونَ ۚ وَمَنْ يَسْتَنْكِفْ عَنْ عِبَادَتِهِ وَيَسْتَكْبِرْ فَسَيَحْشُرُهُمْ إِلَيْهِ جَمِيعًا
Mosih ko ko lati je eru fun Allahu. Bee naa ni awon molaika ti won sunmo Allahu. Enikeni ti o ba ko lati josin fun Un, ti o tun segberaga, (Allahu) yoo ko won jo papo patapata si odo Re
فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَيُوَفِّيهِمْ أُجُورَهُمْ وَيَزِيدُهُمْ مِنْ فَضْلِهِ ۖ وَأَمَّا الَّذِينَ اسْتَنْكَفُوا وَاسْتَكْبَرُوا فَيُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا وَلَا يَجِدُونَ لَهُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَلِيًّا وَلَا نَصِيرًا
Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere, (Allahu) yoo san won ni esan rere won. O si maa se alekun fun won ninu oore ajulo Re. Ni ti awon t’o ba si ko (lati josin fun Allahu), ti won si segberaga, (Allahu) yoo je won niya eleta-elero. Won ko si nii ri alatileyin tabi alaranse kan leyin Allahu
يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمْ بُرْهَانٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَأَنْزَلْنَا إِلَيْكُمْ نُورًا مُبِينًا
Eyin eniyan, dajudaju eri oro ti de ba yin lati odo Oluwa yin. A si tun so imole t’o yanju kale fun yin

Choose other languages: