Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #14 Translated in Yoruba

وَأَلْقِ عَصَاكَ ۚ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ لَا تَخَفْ إِنِّي لَا يَخَافُ لَدَيَّ الْمُرْسَلُونَ
Ju opa re sile. (O si se bee.) Amo nigba ti o ri i t’o n yira pada bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo. Ko si pada. (Allahu so pe:) Musa, ma se paya. Dajudaju awon Ojise ki i paya lodo Mi
إِلَّا مَنْ ظَلَمَ ثُمَّ بَدَّلَ حُسْنًا بَعْدَ سُوءٍ فَإِنِّي غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ayafi eni ti o ba sabosi, leyin naa ti o yi i pada si rere leyin aburu. Dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun
وَأَدْخِلْ يَدَكَ فِي جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ ۖ فِي تِسْعِ آيَاتٍ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَقَوْمِهِ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ
Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re. O si maa jade ni funfun, ti ki i se ti aburu. (Eyi wa) ninu awon ami mesan-an (ti o maa mu lo) ba Fir‘aon ati awon eniyan re. Dajudaju won je ijo obileje
فَلَمَّا جَاءَتْهُمْ آيَاتُنَا مُبْصِرَةً قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ
Nigba ti awon ami Wa, t’o foju han kedere, si de ba won, won wi pe: “Eyi ni idan ponnbele.”
وَجَحَدُوا بِهَا وَاسْتَيْقَنَتْهَا أَنْفُسُهُمْ ظُلْمًا وَعُلُوًّا ۚ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ
Won tako o pelu abosi ati igberaga, emi won si ni amodaju pe ododo ni. Nitori naa, woye si bi atubotan awon obileje ti ri

Choose other languages: