Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #32 Translated in Yoruba

قَالَ ذَٰلِكَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ ۖ أَيَّمَا الْأَجَلَيْنِ قَضَيْتُ فَلَا عُدْوَانَ عَلَيَّ ۖ وَاللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ
(Musa) so pe: “(Adehun) yii wa laaarin emi ati iwo. Eyikeyii ti mo ba mu se ninu adehun mejeeji naa, iwo ko gbodo sabosi si mi. Allahu si ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”
فَلَمَّا قَضَىٰ مُوسَى الْأَجَلَ وَسَارَ بِأَهْلِهِ آنَسَ مِنْ جَانِبِ الطُّورِ نَارًا قَالَ لِأَهْلِهِ امْكُثُوا إِنِّي آنَسْتُ نَارًا لَعَلِّي آتِيكُمْ مِنْهَا بِخَبَرٍ أَوْ جَذْوَةٍ مِنَ النَّارِ لَعَلَّكُمْ تَصْطَلُونَ
Nigba ti Musa pari akoko naa, o mu ara ile re rin (irin-ajo). O si ri ina kan ni eba apata. O so fun ara ile re pe: “E duro (sibi na). Emi ri ina kan. O se e se ki ng mu iro kan wa ba yin lati ibe tabi (ki ng mu) ogunna kan wa nitori ki e le ri ohun yena.”
فَلَمَّا أَتَاهَا نُودِيَ مِنْ شَاطِئِ الْوَادِ الْأَيْمَنِ فِي الْبُقْعَةِ الْمُبَارَكَةِ مِنَ الشَّجَرَةِ أَنْ يَا مُوسَىٰ إِنِّي أَنَا اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ
Nigba ti o de ibe, A pe e lati egbe afonifoji ni owo otun (re) ni aye ibukun lati ibi igi naa. (A so pe): “Musa, dajudaju Emi ni Allahu, Oluwa gbogbo eda
وَأَنْ أَلْقِ عَصَاكَ ۖ فَلَمَّا رَآهَا تَهْتَزُّ كَأَنَّهَا جَانٌّ وَلَّىٰ مُدْبِرًا وَلَمْ يُعَقِّبْ ۚ يَا مُوسَىٰ أَقْبِلْ وَلَا تَخَفْ ۖ إِنَّكَ مِنَ الْآمِنِينَ
Ju opa re sile.” (O si ju u sile). Nigba ti o ri i t’o n mira bi eni pe ejo ni, Musa peyin da, o n sa lo, ko si pada. (Allahu so pe): “Musa, maa bo pada, ma si se paya. Dajudaju iwo wa ninu awon olufayabale
اسْلُكْ يَدَكَ فِي جَيْبِكَ تَخْرُجْ بَيْضَاءَ مِنْ غَيْرِ سُوءٍ وَاضْمُمْ إِلَيْكَ جَنَاحَكَ مِنَ الرَّهْبِ ۖ فَذَانِكَ بُرْهَانَانِ مِنْ رَبِّكَ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمًا فَاسِقِينَ
Ti owo re bo (abiya lati ibi) orun ewu re, o si maa jade ni funfun ti ki i se ti aburu. Pa owo re mora si (abiya re) nibi eru. Nitori naa, awon eri meji niwonyi lati odo Oluwa re si Fir‘aon ati awon ijoye re. Dajudaju won je ijo obileje.”

Choose other languages: