Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #93 Translated in Yoruba

لَا يُؤَاخِذُكُمُ اللَّهُ بِاللَّغْوِ فِي أَيْمَانِكُمْ وَلَٰكِنْ يُؤَاخِذُكُمْ بِمَا عَقَّدْتُمُ الْأَيْمَانَ ۖ فَكَفَّارَتُهُ إِطْعَامُ عَشَرَةِ مَسَاكِينَ مِنْ أَوْسَطِ مَا تُطْعِمُونَ أَهْلِيكُمْ أَوْ كِسْوَتُهُمْ أَوْ تَحْرِيرُ رَقَبَةٍ ۖ فَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَصِيَامُ ثَلَاثَةِ أَيَّامٍ ۚ ذَٰلِكَ كَفَّارَةُ أَيْمَانِكُمْ إِذَا حَلَفْتُمْ ۚ وَاحْفَظُوا أَيْمَانَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Allahu ko nii fi ibura ti o bo lenu yin bi yin, sugbon O maa fi awon ibura ti e finnufindo mu wa bi yin. Nitori naa, itanran re ni bibo talika mewaa pelu ounje ti o wa ni iwontun-wonsi ti e n fi bo ara ile yin, tabi ki e raso fun won, tabi ki e tu eru onigbagbo ododo kan sile loko eru. Enikeni ti ko ba ri (eyi se), o maa gba aawe ojo meta. Iyen ni itanran ibura yin nigba ti e ba bura. E so ibura yin. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah Re fun yin, nitori ki e le dupe
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِنَّمَا الْخَمْرُ وَالْمَيْسِرُ وَالْأَنْصَابُ وَالْأَزْلَامُ رِجْسٌ مِنْ عَمَلِ الشَّيْطَانِ فَاجْتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, dajudaju oti, tete, awon orisa ati ise yiyewo, egbin ninu ise Esu ni. Nitori naa, e jinna si i nitori ki e le jere
إِنَّمَا يُرِيدُ الشَّيْطَانُ أَنْ يُوقِعَ بَيْنَكُمُ الْعَدَاوَةَ وَالْبَغْضَاءَ فِي الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ وَيَصُدَّكُمْ عَنْ ذِكْرِ اللَّهِ وَعَنِ الصَّلَاةِ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ مُنْتَهُونَ
Ohun ti Esu n fe ni pe o maa da ota ati ikorira sile laaarin yin nibi oti ati tete. O si fe se yin lori kuro nibi iranti Allahu ati nibi irun kiki. Se eyin ko nii jawo (nibi ise Esu) ni
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَاحْذَرُوا ۚ فَإِنْ تَوَلَّيْتُمْ فَاعْلَمُوا أَنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
E tele ti Allahu, e tele ti Ojise. Ki e si sora. Nitori naa, ti e ba gbunri, ki e mo pe ise-jije ponnbele lojuse awon Ojise Wa
لَيْسَ عَلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جُنَاحٌ فِيمَا طَعِمُوا إِذَا مَا اتَّقَوْا وَآمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ثُمَّ اتَّقَوْا وَآمَنُوا ثُمَّ اتَّقَوْا وَأَحْسَنُوا ۗ وَاللَّهُ يُحِبُّ الْمُحْسِنِينَ
Ko si ibawi fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere nipa ohun ti won je (ninu ounje siwaju ofin) nigba ti won ba ti beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, ti won tun sise rere, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won si gbagbo ni ododo, leyin naa, ti won beru Allahu, ti won tun sise rere. Allahu si feran awon oluse-rere

Choose other languages: