Surah Al-Maeda Ayahs #52 Translated in Yoruba
وَأَنْزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ مُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهِ مِنَ الْكِتَابِ وَمُهَيْمِنًا عَلَيْهِ ۖ فَاحْكُمْ بَيْنَهُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ ۖ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ عَمَّا جَاءَكَ مِنَ الْحَقِّ ۚ لِكُلٍّ جَعَلْنَا مِنْكُمْ شِرْعَةً وَمِنْهَاجًا ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَجَعَلَكُمْ أُمَّةً وَاحِدَةً وَلَٰكِنْ لِيَبْلُوَكُمْ فِي مَا آتَاكُمْ ۖ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ ۚ إِلَى اللَّهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا فَيُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ فِيهِ تَخْتَلِفُونَ
A so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. O n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ninu Tira. O n wa aabo fun awon ofin inu re. Nitori naa, fi ohun ti Allahu sokale dajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won t’o yapa si ohun ti o de ba o ninu ododo. Olukuluku ninu yin ni A ti se ofin ati ilana fun. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe, iba se yin ni ijo kan soso (sinu ’Islam), sugbon nitori ki O le dan yin wo ninu ohun ti O fun yin ni. Nitori naa, e gbawaju nibi ise rere. Odo Allahu ni ibupadasi gbogbo yin patapata. O si maa fun yin ni iro nipa ohun ti e n yapa enu si
وَأَنِ احْكُمْ بَيْنَهُمْ بِمَا أَنْزَلَ اللَّهُ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَهُمْ وَاحْذَرْهُمْ أَنْ يَفْتِنُوكَ عَنْ بَعْضِ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ إِلَيْكَ ۖ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَاعْلَمْ أَنَّمَا يُرِيدُ اللَّهُ أَنْ يُصِيبَهُمْ بِبَعْضِ ذُنُوبِهِمْ ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ لَفَاسِقُونَ
Ati pe ki o fi ohun ti Allahu sokale se idajo laaarin won. Ma se tele ife-inu won. Sora fun won ki won ma baa fooro re kuro nibi apa kan ohun ti Allahu sokale fun o. Ti won ba si gbunri, mo pe Allahu kan fe fi adanwo kan won ni nitori apa kan ese won. Ati pe dajudaju opolopo ninu eniyan ni obileje
أَفَحُكْمَ الْجَاهِلِيَّةِ يَبْغُونَ ۚ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ حُكْمًا لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ
Se idajo igba aimokan ni won n wa ni? Ta ni eni ti o dara ju Allahu lo nibi idajo fun ijo t’o ni amodaju (nipa Re)
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الْيَهُودَ وَالنَّصَارَىٰ أَوْلِيَاءَ ۘ بَعْضُهُمْ أَوْلِيَاءُ بَعْضٍ ۚ وَمَنْ يَتَوَلَّهُمْ مِنْكُمْ فَإِنَّهُ مِنْهُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon yehudi ati nasara ni ore ayo. Apa kan won lore apa kan. Enikeni ti o ba mu won ni ore ayo ninu yin, dajudaju o ti di ara won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
فَتَرَى الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ يُسَارِعُونَ فِيهِمْ يَقُولُونَ نَخْشَىٰ أَنْ تُصِيبَنَا دَائِرَةٌ ۚ فَعَسَى اللَّهُ أَنْ يَأْتِيَ بِالْفَتْحِ أَوْ أَمْرٍ مِنْ عِنْدِهِ فَيُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا أَسَرُّوا فِي أَنْفُسِهِمْ نَادِمِينَ
Nitori naa, o maa ri awon ti aare wa ninu okan won, ti won yoo maa yara lo saaarin won. Won yoo maa wi pe: “A n beru pe ki apadasi igba ma baa kan wa ni.” O sunmo ki Allahu mu isegun tabi ase kan wa lati odo Re. Won yo si di alabaamo lori ohun ti won fi pamo sinu okan won
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
