Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Jathiya Ayahs #15 Translated in Yoruba

هَٰذَا هُدًى ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ لَهُمْ عَذَابٌ مِنْ رِجْزٍ أَلِيمٌ
Eyi ni imona. Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Oluwa won, iya elegbin eleta-elero wa fun won
اللَّهُ الَّذِي سَخَّرَ لَكُمُ الْبَحْرَ لِتَجْرِيَ الْفُلْكُ فِيهِ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِنْ فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Allahu ni Eni ti O ro agbami odo fun yin nitori ki awon oko oju-omi le rin ninu re pelu ase Re ati nitori ki e tun le wa ninu oore Re ati nitori ki e le dupe (fun Un)
وَسَخَّرَ لَكُمْ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا مِنْهُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ
O tun ro ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile patapata fun yin lati odo ara Re. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni arojinle
قُلْ لِلَّذِينَ آمَنُوا يَغْفِرُوا لِلَّذِينَ لَا يَرْجُونَ أَيَّامَ اللَّهِ لِيَجْزِيَ قَوْمًا بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ
So fun awon t’o gbagbo ni ododo pe ki won samoju kuro fun awon ti ko reti awon ojo (ti) Allahu (yoo se aranse fun awon onigbagbo ododo) nitori ki O le san esan fun ijo kan nipa ohun ti won n se nise
مَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ أَسَاءَ فَعَلَيْهَا ۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمْ تُرْجَعُونَ
Enikeni ti o ba se ise rere, fun emi ara re ni. Enikeni ti o ba si se ise aburu, fun emi ara re ni. Leyin naa, odo Oluwa yin ni won yoo da yin pada si

Choose other languages: