Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #99 Translated in Yoruba

قُلْ لَوْ كَانَ فِي الْأَرْضِ مَلَائِكَةٌ يَمْشُونَ مُطْمَئِنِّينَ لَنَزَّلْنَا عَلَيْهِمْ مِنَ السَّمَاءِ مَلَكًا رَسُولًا
So pe: “Ti o ba je pe awon molaika wa lori ile aye, ti won n rin kiri, (ti won n gbe lori ile) pelu ifayabale, A iba so molaika kan kale fun won lati inu sanmo (lati je) Ojise.”
قُلْ كَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۚ إِنَّهُ كَانَ بِعِبَادِهِ خَبِيرًا بَصِيرًا
So pe: “Allahu to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Dajudaju O n je Onimo-ikoko, Oluriran nipa awon erusin Re.”
وَمَنْ يَهْدِ اللَّهُ فَهُوَ الْمُهْتَدِ ۖ وَمَنْ يُضْلِلْ فَلَنْ تَجِدَ لَهُمْ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِهِ ۖ وَنَحْشُرُهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ عُمْيًا وَبُكْمًا وَصُمًّا ۖ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ كُلَّمَا خَبَتْ زِدْنَاهُمْ سَعِيرًا
Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o nii ri awon oluranlowo kan fun won leyin Re. Ati pe A maa ko won jo ni Ojo Ajinde ni idojubole. (Won yoo di) afoju, ayaya ati odi. Ina Jahanamo ni ibugbe won. Nigbakigba ti Ina ba jo loole, A maa salekun jijo (re) fun won
ذَٰلِكَ جَزَاؤُهُمْ بِأَنَّهُمْ كَفَرُوا بِآيَاتِنَا وَقَالُوا أَإِذَا كُنَّا عِظَامًا وَرُفَاتًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ خَلْقًا جَدِيدًا
Iyen ni esan won nitori pe, won sai gbagbo ninu awon ayah Wa. Won si wi pe: “Se nigba ti a ba ti di egungun, ti a si ti jera, se won tun maa gbe wa dide ni eda titun ni?”
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ قَادِرٌ عَلَىٰ أَنْ يَخْلُقَ مِثْلَهُمْ وَجَعَلَ لَهُمْ أَجَلًا لَا رَيْبَ فِيهِ فَأَبَى الظَّالِمُونَ إِلَّا كُفُورًا
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile lagbara lati seda iru won (miiran)? O si maa fun won ni gbedeke akoko kan, ti ko si iyemeji ninu re. Sibesibe awon alabosi ko lati gba afi atako sa

Choose other languages: