Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hashr Ayahs #10 Translated in Yoruba

وَمَا أَفَاءَ اللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ مِنْهُمْ فَمَا أَوْجَفْتُمْ عَلَيْهِ مِنْ خَيْلٍ وَلَا رِكَابٍ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ يُسَلِّطُ رُسُلَهُ عَلَىٰ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo won fun Ojise Re, ti e o gbe esin ati rakunmi sare fun (ti Ojise Re ni). Sugbon Allahu yoo maa fun awon Ojise Re ni agbara lori eni ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
مَا أَفَاءَ اللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ مِنْ أَهْلِ الْقُرَىٰ فَلِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ كَيْ لَا يَكُونَ دُولَةً بَيْنَ الْأَغْنِيَاءِ مِنْكُمْ ۚ وَمَا آتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانْتَهُوا ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۖ إِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Ohunkohun ti Allahu ba da pada lati odo awon ara ilu fun Ojise Re, (o je) ti Allahu ati ti Ojise ati ti awon ibatan, awon omo orukan, awon talika ati onirin-ajo ti agara da nitori ki o ma baa je adapin laaarin awon oloro ninu yin. Ohunkohun ti Ojise ba fun yin, e gba a. Ohunkohun ti o ba si ko fun yin, e jawo ninu re. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu le nibi iya
لِلْفُقَرَاءِ الْمُهَاجِرِينَ الَّذِينَ أُخْرِجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ وَأَمْوَالِهِمْ يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانًا وَيَنْصُرُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الصَّادِقُونَ
(Ikogun naa tun wa fun) awon alaini, (iyen,) al-Muhajirun, awon ti won le jade kuro ninu ile won ati nibi dukia won, ti won si n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu, ti won si n saranse fun (esin) Allahu ati Ojise Re. Awon wonyen ni awon olododo
وَالَّذِينَ تَبَوَّءُوا الدَّارَ وَالْإِيمَانَ مِنْ قَبْلِهِمْ يُحِبُّونَ مَنْ هَاجَرَ إِلَيْهِمْ وَلَا يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمْ حَاجَةً مِمَّا أُوتُوا وَيُؤْثِرُونَ عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ وَلَوْ كَانَ بِهِمْ خَصَاصَةٌ ۚ وَمَنْ يُوقَ شُحَّ نَفْسِهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Awon t’o n gbe ninu ilu Modinah, ti won si ni igbagbo ododo siwaju won, won nifee awon t’o fi ilu Mokkah sile wa si odo won (ni ilu Modinah). Won ko si ni bukata kan ninu igba-aya won si nnkan ti won fun won. Won si n gbe ajulo fun won lori emi ara won, koda ki o je pe awon gan-an ni bukata (si ohun ti won fun won). Enikeni ti A ba so nibi ahun ati okanjua inu emi re, awon wonyen, awon ni olujere
وَالَّذِينَ جَاءُوا مِنْ بَعْدِهِمْ يَقُولُونَ رَبَّنَا اغْفِرْ لَنَا وَلِإِخْوَانِنَا الَّذِينَ سَبَقُونَا بِالْإِيمَانِ وَلَا تَجْعَلْ فِي قُلُوبِنَا غِلًّا لِلَّذِينَ آمَنُوا رَبَّنَا إِنَّكَ رَءُوفٌ رَحِيمٌ
Awon t’o de leyin won n so pe: "Oluwa wa, forijin awa ati awon omo iya wa t’o siwaju wa ninu igbagbo ododo. Ma se je ki inunibini wa ninu okan wa si awon t’o gbagbo ni ododo. Oluwa wa, dajudaju Iwo ni Alaaanu, Asake-orun

Choose other languages: