Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hashr Ayahs #18 Translated in Yoruba

لَا يُقَاتِلُونَكُمْ جَمِيعًا إِلَّا فِي قُرًى مُحَصَّنَةٍ أَوْ مِنْ وَرَاءِ جُدُرٍ ۚ بَأْسُهُمْ بَيْنَهُمْ شَدِيدٌ ۚ تَحْسَبُهُمْ جَمِيعًا وَقُلُوبُهُمْ شَتَّىٰ ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَوْمٌ لَا يَعْقِلُونَ
Won ko le parapo doju ija ko yin afi (ki won) wa ninu odi ilu tabi (ki won wa) leyin awon ogiri. Ogun aarin ara won gan-an le. O n lero pe won wa ni irepo ni, otooto si ni okan won wa. Iyen nitori pe dajudaju awon ni ijo ti ko ni laakaye
كَمَثَلِ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ قَرِيبًا ۖ ذَاقُوا وَبَالَ أَمْرِهِمْ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Apeere won da bi awon t’o siwaju won ti ko ti i pe lo titi. Won to aburu oro ara won wo. Iya eleta-elero si wa fun won
كَمَثَلِ الشَّيْطَانِ إِذْ قَالَ لِلْإِنْسَانِ اكْفُرْ فَلَمَّا كَفَرَ قَالَ إِنِّي بَرِيءٌ مِنْكَ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ
Apeere won da bi Esu nigba ti o ba wi fun eniyan pe: "Sai gbagbo." Nigba ti o ba sai gbagbo (tan), o maa wi pe: "Dajudaju emi yowo-yose kuro ninu oro re. Dajudaju emi n paya Allahu, Oluwa gbogbo eda
فَكَانَ عَاقِبَتَهُمَا أَنَّهُمَا فِي النَّارِ خَالِدَيْنِ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ
Nitori naa, ikangun awon mejeeji ni pe, dajudaju awon mejeeji yoo wa ninu Ina. Olusegbere ni awon mejeeji ninu re. Iyen si ni esan awon alabosi
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَلْتَنْظُرْ نَفْسٌ مَا قَدَّمَتْ لِغَدٍ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e beru Allahu. Ki emi kan si woye si ohun ti o ti siwaju fun ola (alukiyaamo). E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise

Choose other languages: