Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #19 Translated in Yoruba

مَنْ كَانَ يَظُنُّ أَنْ لَنْ يَنْصُرَهُ اللَّهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ فَلْيَمْدُدْ بِسَبَبٍ إِلَى السَّمَاءِ ثُمَّ لْيَقْطَعْ فَلْيَنْظُرْ هَلْ يُذْهِبَنَّ كَيْدُهُ مَا يَغِيظُ
Enikeni ti o ba lero pe Allahu ko nii ran (Anabi) lowo laye ati lorun, ki o na okun si sanmo leyin naa ki o ge e (iyen ni pe, ki o pokun so). Ki o wo o nigba naa boya ete re le mu (aranse) t’o n binu si kuro (lodo Anabi s.a.w)
وَكَذَٰلِكَ أَنْزَلْنَاهُ آيَاتٍ بَيِّنَاتٍ وَأَنَّ اللَّهَ يَهْدِي مَنْ يُرِيدُ
Bayen ni A se so o kale ni awon ayah t’o yanju. Dajudaju Allahu n to eni ti O ba fe si ona
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَادُوا وَالصَّابِئِينَ وَالنَّصَارَىٰ وَالْمَجُوسَ وَالَّذِينَ أَشْرَكُوا إِنَّ اللَّهَ يَفْصِلُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo ati awon t’o di yehudi, awon sobi’un, awon kristieni, awon mojus ati awon t’o sebo, dajudaju Allahu yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde. Dajudaju Allahu ni Arinu-rode gbogbo nnkan
أَلَمْ تَرَ أَنَّ اللَّهَ يَسْجُدُ لَهُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ وَالشَّمْسُ وَالْقَمَرُ وَالنُّجُومُ وَالْجِبَالُ وَالشَّجَرُ وَالدَّوَابُّ وَكَثِيرٌ مِنَ النَّاسِ ۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيْهِ الْعَذَابُ ۗ وَمَنْ يُهِنِ اللَّهُ فَمَا لَهُ مِنْ مُكْرِمٍ ۚ إِنَّ اللَّهَ يَفْعَلُ مَا يَشَاءُ ۩
Se o o ri i pe dajudaju Allahu ni awon t’o n be ninu awon sanmo ati awon t’o n be lori ile, ati oorun, osupa, awon irawo, awon apata, awon igi, awon nnkan elemii ati opolopo ninu awon eniyan n fori kanle fun? Opolopo si tun ni iya ti ko le lori. Enikeni ti Allahu ba fi abuku kan, ko si eni kan ti o maa se aponle re. Dajudaju Allahu n se ohun ti O ba fe
هَٰذَانِ خَصْمَانِ اخْتَصَمُوا فِي رَبِّهِمْ ۖ فَالَّذِينَ كَفَرُوا قُطِّعَتْ لَهُمْ ثِيَابٌ مِنْ نَارٍ يُصَبُّ مِنْ فَوْقِ رُءُوسِهِمُ الْحَمِيمُ
Awon onija meji (kan) niyi, won n tako ara won nipa Oluwa won. Nitori naa, awon t’o sai gbagbo, won maa ge aso Ina fun won, won si maa da omi gbigbona le won lori lati oke ori won

Choose other languages: