Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #78 Translated in Yoruba

ثُمَّ قَسَتْ قُلُوبُكُمْ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَالْحِجَارَةِ أَوْ أَشَدُّ قَسْوَةً ۚ وَإِنَّ مِنَ الْحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنْهُ الْأَنْهَارُ ۚ وَإِنَّ مِنْهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخْرُجُ مِنْهُ الْمَاءُ ۚ وَإِنَّ مِنْهَا لَمَا يَهْبِطُ مِنْ خَشْيَةِ اللَّهِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Leyin naa, okan yin le leyin iyen. O si da bi okuta tabi lile t’o lagbara ju bee lo. Dajudaju o n be ninu awon okuta ti awon odo n san jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o maa san kankan. Omi si maa jade lati inu re. Dajudaju o tun n be ninu won ti o n wo lule gbi fun ipaya Allahu. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise
أَفَتَطْمَعُونَ أَنْ يُؤْمِنُوا لَكُمْ وَقَدْ كَانَ فَرِيقٌ مِنْهُمْ يَسْمَعُونَ كَلَامَ اللَّهِ ثُمَّ يُحَرِّفُونَهُ مِنْ بَعْدِ مَا عَقَلُوهُ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Nje e lero pe won yoo gba yin gbo, nigba ti o je pe igun kan ninu won kuku n gbo oro Allahu. Leyin naa, won a yi i pada sodi leyin ti won ti gbo o ye; won si mo
وَإِذَا لَقُوا الَّذِينَ آمَنُوا قَالُوا آمَنَّا وَإِذَا خَلَا بَعْضُهُمْ إِلَىٰ بَعْضٍ قَالُوا أَتُحَدِّثُونَهُمْ بِمَا فَتَحَ اللَّهُ عَلَيْكُمْ لِيُحَاجُّوكُمْ بِهِ عِنْدَ رَبِّكُمْ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Nigba ti won ba si pade awon t’o gbagbo ni ododo, won a wi pe: “A gbagbo.” Nigba ti o ba si ku apa kan won ku apa kan, won a wi pe: “Se ki i se pe e n ba won soro nipa ohun ti Allahu ti sipaya re fun yin, ki won le fi ja yin niyan ni odo Oluwa yin? Se e o se laakaye ni!”
أَوَلَا يَعْلَمُونَ أَنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ
Se won ko mo pe dajudaju Allahu mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re
وَمِنْهُمْ أُمِّيُّونَ لَا يَعْلَمُونَ الْكِتَابَ إِلَّا أَمَانِيَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَظُنُّونَ
Ati pe o wa ninu won, awon alaimoonkomoonka, ti won ko nimo nipa Tira afi awon oro-iro. Ki ni won (n so) bi ko se pe won n saroso

Choose other languages: