Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #219 Translated in Yoruba

يَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنْفِقُونَ ۖ قُلْ مَا أَنْفَقْتُمْ مِنْ خَيْرٍ فَلِلْوَالِدَيْنِ وَالْأَقْرَبِينَ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ ۗ وَمَا تَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ بِهِ عَلِيمٌ
Won n bi o leere pe ki ni awon yo maa nawo si. So pe: "Ohun ti e ba na ninu ohun rere, ki o maa je ti awon obi mejeeji, awon ebi, awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da). Ohunkohun ti e ba se ninu ohun rere, dajudaju Allahu ni Onimo nipa re
كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِتَالُ وَهُوَ كُرْهٌ لَكُمْ ۖ وَعَسَىٰ أَنْ تَكْرَهُوا شَيْئًا وَهُوَ خَيْرٌ لَكُمْ ۖ وَعَسَىٰ أَنْ تُحِبُّوا شَيْئًا وَهُوَ شَرٌّ لَكُمْ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ وَأَنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
A se ogun esin ni oran-anyan le yin lori, ohun ikorira si ni fun yin. O si le je pe e korira kini kan, ki ohun naa si je oore fun yin. O si tun le je pe e nifee si kini kan, ki ohun naa si je aburu fun yin. Allahu nimo, eyin ko si nimo
يَسْأَلُونَكَ عَنِ الشَّهْرِ الْحَرَامِ قِتَالٍ فِيهِ ۖ قُلْ قِتَالٌ فِيهِ كَبِيرٌ ۖ وَصَدٌّ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَكُفْرٌ بِهِ وَالْمَسْجِدِ الْحَرَامِ وَإِخْرَاجُ أَهْلِهِ مِنْهُ أَكْبَرُ عِنْدَ اللَّهِ ۚ وَالْفِتْنَةُ أَكْبَرُ مِنَ الْقَتْلِ ۗ وَلَا يَزَالُونَ يُقَاتِلُونَكُمْ حَتَّىٰ يَرُدُّوكُمْ عَنْ دِينِكُمْ إِنِ اسْتَطَاعُوا ۚ وَمَنْ يَرْتَدِدْ مِنْكُمْ عَنْ دِينِهِ فَيَمُتْ وَهُوَ كَافِرٌ فَأُولَٰئِكَ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Won n bi o leere nipa ogun jija ninu osu owo. So pe: "Ese nla ni ogun jija ninu re. Ati pe siseri awon eniyan kuro l’oju ona (esin) Allahu, sise aigbagbo ninu Allahu, didi awon musulumi lowo lati wo inu Mosalasi Haram ati lile awon musulumi jade kuro ninu re, (iwonyi) tun tobi julo ni ese ni odo Allahu." Ifooro si buru ju ipaniyan lo. Won ko ni yee gbogun ti yin titi won yo fi se yin lori kuro ninu esin yin, ti won ba lagbara (ona lati se bee). Enikeni ninu yin ti o ba seri kuroninu esin re, ti o si ku si ipo keferi, nitori naa awon wonyen ni awon ise won ti baje ni aye ati ni orun. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ هَاجَرُوا وَجَاهَدُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ أُولَٰئِكَ يَرْجُونَ رَحْمَتَ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, awon t’o gbe ilu (won) ju sile ati awon t’o jagun fun esin Allahu, awon wonyen n reti ike Allahu. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun
يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ ۖ قُلْ فِيهِمَا إِثْمٌ كَبِيرٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَإِثْمُهُمَا أَكْبَرُ مِنْ نَفْعِهِمَا ۗ وَيَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنْفِقُونَ قُلِ الْعَفْوَ ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ
Won n bi o leere nipa oti ati tete. So pe: "Ese nla ati awon anfaani kan wa ninu mejeeji fun awon eniyan. Ese mejeeji si tobi ju anfaani won lo." Won tun n bi o leere pe ki ni awon yo maa na ni saraa. So pe: “Ohun ti o ba seku leyin ti e ba ti gbo bukata inu ile tan (ni ki e fi se saraa).” Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah fun yin nitori ki e le ronu jinle

Choose other languages: