Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #167 Translated in Yoruba

وَإِلَٰهُكُمْ إِلَٰهٌ وَاحِدٌ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ الرَّحْمَٰنُ الرَّحِيمُ
Olohun yin, Olohun Okan soso ni. Ko si olohun kan ti ijosin to si ayafi Oun, Ajoke-aye, Asake-orun
إِنَّ فِي خَلْقِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَالْفُلْكِ الَّتِي تَجْرِي فِي الْبَحْرِ بِمَا يَنْفَعُ النَّاسَ وَمَا أَنْزَلَ اللَّهُ مِنَ السَّمَاءِ مِنْ مَاءٍ فَأَحْيَا بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِنْ كُلِّ دَابَّةٍ وَتَصْرِيفِ الرِّيَاحِ وَالسَّحَابِ الْمُسَخَّرِ بَيْنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
Dajudaju awon ami wa ninu iseda awon sanmo ati ile, itelentele ati iyato oru ati osan, ati awon oko oju-omi t’o n rin lori omi pelu (riru) ohun t’o n se awon eniyan ni anfaani, ati ohun ti Allahu n sokale ni omi ojo lati sanmo, ti O si n fi so ile di aye leyin ti o ti ku, ati (bi) O se fon gbogbo eranko ka si ori ile, ati iyipada ategun ati esujo ti A teba laaarin sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n se laakaye
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَتَّخِذُ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَنْدَادًا يُحِبُّونَهُمْ كَحُبِّ اللَّهِ ۖ وَالَّذِينَ آمَنُوا أَشَدُّ حُبًّا لِلَّهِ ۗ وَلَوْ يَرَى الَّذِينَ ظَلَمُوا إِذْ يَرَوْنَ الْعَذَابَ أَنَّ الْقُوَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا وَأَنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعَذَابِ
O si n be ninu awon eniyan, eni ti n josin fun awon orisa leyin Allahu. Won nifee won gege bi ife (to ye ki won ni si) Allahu. Awon t’o gbagbo ni ododo si le julo ninu ife si
إِذْ تَبَرَّأَ الَّذِينَ اتُّبِعُوا مِنَ الَّذِينَ اتَّبَعُوا وَرَأَوُا الْعَذَابَ وَتَقَطَّعَتْ بِهِمُ الْأَسْبَابُ
(Ranti) nigba ti awon ti won tele (ninu aigbagbo) maa yowo yose kuro ninu oro awon t’o tele won; (nigba ti) won ba foju ri Iya, ti ohun t’o so won po si ja patapata
وَقَالَ الَّذِينَ اتَّبَعُوا لَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَتَبَرَّأَ مِنْهُمْ كَمَا تَبَرَّءُوا مِنَّا ۗ كَذَٰلِكَ يُرِيهِمُ اللَّهُ أَعْمَالَهُمْ حَسَرَاتٍ عَلَيْهِمْ ۖ وَمَا هُمْ بِخَارِجِينَ مِنَ النَّارِ
Awon t’o tele won yo si wi pe: “Ti o ba je pe dajudaju ipadawaye le wa fun wa ni, awa iba yowo yose kuro ninu oro won ni gege bi won se yowo yose kuro ninu oro wa.” Bayen ni Allahu yo se fi awon ise won han won ni (ise) ofo fun won. Won ko si nii jade kuro ninu Ina

Choose other languages: