Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #87 Translated in Yoruba

فَأَنْجَيْنَاهُ وَأَهْلَهُ إِلَّا امْرَأَتَهُ كَانَتْ مِنَ الْغَابِرِينَ
Nigba naa, A gba oun ati ebi re la afi iyawo re ti o wa ninu awon t’o seku leyin sinu iparun
وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ مَطَرًا ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُجْرِمِينَ
A ro ojo le won lori taara. Wo bi ikangun awon elese se ri
وَإِلَىٰ مَدْيَنَ أَخَاهُمْ شُعَيْبًا ۗ قَالَ يَا قَوْمِ اعْبُدُوا اللَّهَ مَا لَكُمْ مِنْ إِلَٰهٍ غَيْرُهُ ۖ قَدْ جَاءَتْكُمْ بَيِّنَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ فَأَوْفُوا الْكَيْلَ وَالْمِيزَانَ وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ بَعْدَ إِصْلَاحِهَا ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
(A tun ran eni kan) si awon ara Modyan, arakunrin won, Su‘aeb. O so pe: "Eyin ijo mi, e josin fun Allahu. E e ni olohun miiran leyin Re. Dajudaju eri t’o yanju ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, e won kongo ati osuwon kun. E ma se din nnkan awon eniyan ku. E si ma se ibaje lori ile leyin atunse re. Iyen si loore julo fun yin ti e ba je onigbagbo ododo
وَلَا تَقْعُدُوا بِكُلِّ صِرَاطٍ تُوعِدُونَ وَتَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ مَنْ آمَنَ بِهِ وَتَبْغُونَهَا عِوَجًا ۚ وَاذْكُرُوا إِذْ كُنْتُمْ قَلِيلًا فَكَثَّرَكُمْ ۖ وَانْظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُفْسِدِينَ
E ma se lugo si gbogbo ona lati maa deruba awon eniyan; e n seri eni t’o gbagbo kuro loju ona (esin) Allahu, e si n fe k’o wo. E ranti o, nigba ti e kere (lonka), Allahu so yin di pupo. E si wo bi ikangun awon obileje se ri
وَإِنْ كَانَ طَائِفَةٌ مِنْكُمْ آمَنُوا بِالَّذِي أُرْسِلْتُ بِهِ وَطَائِفَةٌ لَمْ يُؤْمِنُوا فَاصْبِرُوا حَتَّىٰ يَحْكُمَ اللَّهُ بَيْنَنَا ۚ وَهُوَ خَيْرُ الْحَاكِمِينَ
Ti o ba je pe igun kan ninu yin gbagbo ninu ohun ti Won fi ran mi nise, ti igun kan ko si gbagbo, nigba naa e se suuru titi Allahu yoo fi se idajo laaarin wa. Oun si loore julo ninu awon oludajo

Choose other languages: