Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #33 Translated in Yoruba

قُلْ أَمَرَ رَبِّي بِالْقِسْطِ ۖ وَأَقِيمُوا وُجُوهَكُمْ عِنْدَ كُلِّ مَسْجِدٍ وَادْعُوهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ ۚ كَمَا بَدَأَكُمْ تَعُودُونَ
So pe: “Oluwa mi p’ase sise deede. Ki e si doju yin ko (Allahu) ni gbogbo mosalasi. E pe E (ki e je) olusafomo-esin fun Un. Gege bi O se da yin (ti e fi di alaaye), e maa pada (di alaaye leyin iku yin).”
فَرِيقًا هَدَىٰ وَفَرِيقًا حَقَّ عَلَيْهِمُ الضَّلَالَةُ ۗ إِنَّهُمُ اتَّخَذُوا الشَّيَاطِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ اللَّهِ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ مُهْتَدُونَ
Apa kan ni O fi mona, apa kan si ni isina ko le lori. (Nitori pe) dajudaju won mu awon esu ni ore leyin Allahu. Won si n lero pe dajudaju awon ni olumona
يَا بَنِي آدَمَ خُذُوا زِينَتَكُمْ عِنْدَ كُلِّ مَسْجِدٍ وَكُلُوا وَاشْرَبُوا وَلَا تُسْرِفُوا ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ
Omo (Anabi) Adam, e wo (aso) oso yin nigbakigba ti e ba n lo si mosalasi. E je, e mu, ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa
قُلْ مَنْ حَرَّمَ زِينَةَ اللَّهِ الَّتِي أَخْرَجَ لِعِبَادِهِ وَالطَّيِّبَاتِ مِنَ الرِّزْقِ ۚ قُلْ هِيَ لِلَّذِينَ آمَنُوا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا خَالِصَةً يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ
So pe: “Ta l’o se oso Allahu, ti O mu jade fun awon erusin Re ati awon nnkan daadaa ninu arisiki ni eewo?” So pe: “O wa fun awon t’o gbagbo lododo ninu isemi aye. Tiwon nikan si ni l’Ojo Ajinde." Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo.”
قُلْ إِنَّمَا حَرَّمَ رَبِّيَ الْفَوَاحِشَ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَمَا بَطَنَ وَالْإِثْمَ وَالْبَغْيَ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَأَنْ تُشْرِكُوا بِاللَّهِ مَا لَمْ يُنَزِّلْ بِهِ سُلْطَانًا وَأَنْ تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ
So pe: "Ohun ti Oluwa mi se ni eewo ni awon iwa ibaje – eyi t’o foju han ninu re ati eyi t’o pamo –, iwa ese, ote sise lai letoo, biba Allahu wa akegbe – eyi ti ko so eri kan kale fun – ati sise afiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu

Choose other languages: