Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #189 Translated in Yoruba

أَوَلَمْ يَنْظُرُوا فِي مَلَكُوتِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ مِنْ شَيْءٍ وَأَنْ عَسَىٰ أَنْ يَكُونَ قَدِ اقْتَرَبَ أَجَلُهُمْ ۖ فَبِأَيِّ حَدِيثٍ بَعْدَهُ يُؤْمِنُونَ
Se won ko wo ijoba awon sanmo ati ile pelu gbogbo nnkan ti Allahu da? Amo sa o le je pe Akoko iku won ti sunmo. Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re? “oro wo ninu oro al-Ƙur’an ni won yoo gbagbo leyin ti ojo iku won ba de tabi leyin ti ojo Ajinde ba sele? Bi won ba pada gba oro al-Ƙu’an gbo lojo iku won tabi lojo Ajinde ko le wulo fun won mo oro iro wo ni won yoo gbagbo leyin ti al-Ƙur’an ti mu oro ododo wa? Se awon irori igba aimokan ati awon asa aimokan eyi ti iran eni kookan jogun ba lati odo awon baba nla won ti won ki i se Ojise Olohun se awon irori won ati awon asa iborisa won ni won yoo maa lo leyin al-Ƙur’an? Eyi gan-an ni itumo “fabi ’ayyi hadithin ba‘dahu yu’minun” ninu surah al-Jathiyah; 45:6 nitori pe gbolohun t’o siwaju re ni ibere ayah naa n soro nipa bi al-Ƙur’an se je oro ododo. Eyi wa tumo si pe
مَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَا هَادِيَ لَهُ ۚ وَيَذَرُهُمْ فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ
Enikeni ti Allahu ba si lona ko le si afinimona kan fun un. (Allahu) yo si fi won sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida
يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا ۖ قُلْ إِنَّمَا عِلْمُهَا عِنْدَ رَبِّي ۖ لَا يُجَلِّيهَا لِوَقْتِهَا إِلَّا هُوَ ۚ ثَقُلَتْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا تَأْتِيكُمْ إِلَّا بَغْتَةً ۗ يَسْأَلُونَكَ كَأَنَّكَ حَفِيٌّ عَنْهَا ۖ قُلْ إِنَّمَا عِلْمُهَا عِنْدَ اللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Won n bi o leere nipa Akoko naa pe igba wo ni isele re. So pe: “Odo Oluwa mi nikan ni imo re wa. Ko si eni t’o le safi han Akoko re afi Oun. O soro (lati mo) fun awon ara sanmo ati ara ile. Ko nii de ba yin afi lojiji.” Won tun n bi o leere bi eni pe iwo nimo nipa re. So pe: “Odo Oluwa mi nikan ni imo re wa, sugbon opolopo eniyan ni ko mo.”
قُلْ لَا أَمْلِكُ لِنَفْسِي نَفْعًا وَلَا ضَرًّا إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۚ وَلَوْ كُنْتُ أَعْلَمُ الْغَيْبَ لَاسْتَكْثَرْتُ مِنَ الْخَيْرِ وَمَا مَسَّنِيَ السُّوءُ ۚ إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ وَبَشِيرٌ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
So pe: “Emi ko ni agbara anfaani tabi inira kan ti mo le fi kan ara mi ayafi ohun ti Allahu ba fe. Ti o ba je pe mo ni imo ikoko ni, emi iba ti ko ohun pupo jo ninu oore aye (si odo mi) ati pe aburu aye iba ti kan mi. Ta ni emi bi ko se olukilo ati oniroo idunnu fun ijo onigbagbo ododo.”
هُوَ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ وَجَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا لِيَسْكُنَ إِلَيْهَا ۖ فَلَمَّا تَغَشَّاهَا حَمَلَتْ حَمْلًا خَفِيفًا فَمَرَّتْ بِهِ ۖ فَلَمَّا أَثْقَلَتْ دَعَوَا اللَّهَ رَبَّهُمَا لَئِنْ آتَيْتَنَا صَالِحًا لَنَكُونَنَّ مِنَ الشَّاكِرِينَ
(Allahu) Oun ni Eni t’O da yin lati ara emi eyo kan. O si da aya fun un lati ara re nitori ki o le jegbadun igbepo pelu re. Nigba ti oko sunmo iyawo re, ti o si ru eru (ato) fifuye. O si ru u kiri. Nigba ti o si diwo dise sinu tan, awon mejeeji pe Allahu Oluwa won pe: “Ti O ba fun wa ni omo rere (t’o pe ni eda), dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.”

Choose other languages: