Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #161 Translated in Yoruba

الَّذِينَ يَتَّبِعُونَ الرَّسُولَ النَّبِيَّ الْأُمِّيَّ الَّذِي يَجِدُونَهُ مَكْتُوبًا عِنْدَهُمْ فِي التَّوْرَاةِ وَالْإِنْجِيلِ يَأْمُرُهُمْ بِالْمَعْرُوفِ وَيَنْهَاهُمْ عَنِ الْمُنْكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ الطَّيِّبَاتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيْهِمُ الْخَبَائِثَ وَيَضَعُ عَنْهُمْ إِصْرَهُمْ وَالْأَغْلَالَ الَّتِي كَانَتْ عَلَيْهِمْ ۚ فَالَّذِينَ آمَنُوا بِهِ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ وَاتَّبَعُوا النُّورَ الَّذِي أُنْزِلَ مَعَهُ ۙ أُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Awon t’o n tele Ojise naa, Anabi alaimoonkomoonka, eni ti won yoo ba akosile nipa re lodo won ninu at-Taorah ati al-’Injil, ti o n pa won lase ohun rere, ti o n ko ohun buruku fun won, ti o n se awon nnkan daadaa letoo fun won, ti o si n se awon nnkan aidaa leewo fun won, ti o tun maa gbe eru (adehun t’o wuwo) ati ajaga t’o n be lorun won kuro fun won; awon t’o gbagbo ninu re, ti won bu iyi fun un, ti won ran an lowo, ti won si tele imole naa (iyen, al-Ƙur’an) ti A sokale fun un, awon wonyen ni olujere
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ جَمِيعًا الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ النَّبِيِّ الْأُمِّيِّ الَّذِي يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَكَلِمَاتِهِ وَاتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمْ تَهْتَدُونَ
So pe: "Eyin eniyan, dajudaju emi ni Ojise Allahu si gbogbo yin patapata. (Allahu) Eni t’O ni ijoba awon sanmo ati ile. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Nitori naa, e gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re. Anabi alaimoonkomoonka, eni t’o gbagbo ninu Allahu ati awon oro Re. E tele e nitori ki e le mona
وَمِنْ قَوْمِ مُوسَىٰ أُمَّةٌ يَهْدُونَ بِالْحَقِّ وَبِهِ يَعْدِلُونَ
O wa ninu ijo (Anabi) Musa, ijo kan t’o n fi ododo to (awon eniyan) sona. Won si n se eto pelu re
وَقَطَّعْنَاهُمُ اثْنَتَيْ عَشْرَةَ أَسْبَاطًا أُمَمًا ۚ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ إِذِ اسْتَسْقَاهُ قَوْمُهُ أَنِ اضْرِبْ بِعَصَاكَ الْحَجَرَ ۖ فَانْبَجَسَتْ مِنْهُ اثْنَتَا عَشْرَةَ عَيْنًا ۖ قَدْ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٍ مَشْرَبَهُمْ ۚ وَظَلَّلْنَا عَلَيْهِمُ الْغَمَامَ وَأَنْزَلْنَا عَلَيْهِمُ الْمَنَّ وَالسَّلْوَىٰ ۖ كُلُوا مِنْ طَيِّبَاتِ مَا رَزَقْنَاكُمْ ۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِنْ كَانُوا أَنْفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ
A si pin won si iran mejila ni ijo-ijo. A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa, nigba ti awon eniyan re wa omi wa si odo re, pe: “Fi opa owo re na apata.” (O se bee) orisun omi mejila si seyo lara re. Ijo kookan si ti da ibumu won mo. A tun fi esujo siji bo won. A so (ohun mimu) monnu ati (ohun jije) salwa kale fun won. E je ninu awon nnkan daadaa ti A pese fun yin. Won ko si se abosi si Wa, sugbon emi ara won ni won n sabosi si
وَإِذْ قِيلَ لَهُمُ اسْكُنُوا هَٰذِهِ الْقَرْيَةَ وَكُلُوا مِنْهَا حَيْثُ شِئْتُمْ وَقُولُوا حِطَّةٌ وَادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا نَغْفِرْ لَكُمْ خَطِيئَاتِكُمْ ۚ سَنَزِيدُ الْمُحْسِنِينَ
(E ranti) nigba ti A so fun won pe: “E wo inu ilu yii. E maa je ninu re nibikibi ti e ba fe. Ki e si so pe: ‘Ha ese wa danu.’ E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. A maa fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere.”

Choose other languages: