Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #54 Translated in Yoruba

وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ يَتَوَفَّى الَّذِينَ كَفَرُوا ۙ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ وَذُوقُوا عَذَابَ الْحَرِيقِ
Ti o ba je pe iwo ri i nigba ti awon molaika ba n gba emi awon t’o sai gbagbo ni, ti won n lu oju won ati eyin won, (won si maa so fun won pe), “E to iya Ina jonijoni wo.”
ذَٰلِكَ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيكُمْ وَأَنَّ اللَّهَ لَيْسَ بِظَلَّامٍ لِلْعَبِيدِ
Iyen nitori ohun ti owo yin ti siwaju. Ati pe dajudaju Allahu ko nii se abosi fun awon eru (Re)
كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَفَرُوا بِآيَاتِ اللَّهِ فَأَخَذَهُمُ اللَّهُ بِذُنُوبِهِمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ قَوِيٌّ شَدِيدُ الْعِقَابِ
(Isesi awon alaigbagbo) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won - won sai gbagbo ninu awon ayah Allahu. - Nitori naa, Allahu mu won nitori ese won. Dajudaju Allahu ni Alagbara, O le nibi iya
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ لَمْ يَكُ مُغَيِّرًا نِعْمَةً أَنْعَمَهَا عَلَىٰ قَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنْفُسِهِمْ ۙ وَأَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu ko nii se iyipada idera ti O se fun ijo kan titi won yoo fi se iyipada nnkan ti n be lodo ara won. Dajudaju Allahu si ni Olugbo, Onimo
كَدَأْبِ آلِ فِرْعَوْنَ ۙ وَالَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَذَّبُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ فَأَهْلَكْنَاهُمْ بِذُنُوبِهِمْ وَأَغْرَقْنَا آلَ فِرْعَوْنَ ۚ وَكُلٌّ كَانُوا ظَالِمِينَ
(Isesi awon alaimoore) da bi isesi awon eniyan Fir‘aon ati awon t’o siwaju won, ti won pe awon ayah Oluwa won niro. Nitori naa, A pa won run nitori ese won; A si te awon eniyan Fir‘aon ri sinu agbami. Gbogbo won si je alabosi

Choose other languages: