Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anfal Ayahs #44 Translated in Yoruba

وَإِنْ تَوَلَّوْا فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ مَوْلَاكُمْ ۚ نِعْمَ الْمَوْلَىٰ وَنِعْمَ النَّصِيرُ
Ti won ba si gbunri (kuro ninu igbagbo), e mo pe dajudaju Allahu ni Alafeyinti yin. O dara ni Alafeyinti. O si dara ni Alaranse
وَاعْلَمُوا أَنَّمَا غَنِمْتُمْ مِنْ شَيْءٍ فَأَنَّ لِلَّهِ خُمُسَهُ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينِ وَابْنِ السَّبِيلِ إِنْ كُنْتُمْ آمَنْتُمْ بِاللَّهِ وَمَا أَنْزَلْنَا عَلَىٰ عَبْدِنَا يَوْمَ الْفُرْقَانِ يَوْمَ الْتَقَى الْجَمْعَانِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
E mo pe ohunkohun ti e ba ko ni oro ogun, dajudaju ti Allahu ni ida marun-un re. O si wa fun Ojise ati ebi (re) ati awon omo orukan, awon mekunnu ati onirin-ajo (ti agara da), ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu ati nnkan ti A sokale fun erusin Wa ni Ojo ipinya, ojo ti ijo meji pade (loju ogun Badr). Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
إِذْ أَنْتُمْ بِالْعُدْوَةِ الدُّنْيَا وَهُمْ بِالْعُدْوَةِ الْقُصْوَىٰ وَالرَّكْبُ أَسْفَلَ مِنْكُمْ ۚ وَلَوْ تَوَاعَدْتُمْ لَاخْتَلَفْتُمْ فِي الْمِيعَادِ ۙ وَلَٰكِنْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا لِيَهْلِكَ مَنْ هَلَكَ عَنْ بَيِّنَةٍ وَيَحْيَىٰ مَنْ حَيَّ عَنْ بَيِّنَةٍ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَسَمِيعٌ عَلِيمٌ
(E ranti) nigba ti eyin wa ni eti koto t’o sunmo (ilu Modinah), awon (keferi) si wa ni eti koto t’o jinna si (ilu Modinah), awon keferi kan t’o n gun nnkan igun (bo lati irin-ajo okowo), won si wa ni isale odo tiyin. Ti o ba je pe eyin ati awon keferi jo mu ojo fun ogun naa ni, eyin iba yapa adehun naa, sugbon (ogun naa sele bee) nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse; nitori ki eni ti o maa parun (sinu aigbagbo) le parun nipase eri t’o yanju, ki eni t’o si maa ye (ninu igbagbo ododo) le ye nipase eri t’o yanju. Ati pe dajudaju Allahu kuku ni Olugbo, Onimo
إِذْ يُرِيكَهُمُ اللَّهُ فِي مَنَامِكَ قَلِيلًا ۖ وَلَوْ أَرَاكَهُمْ كَثِيرًا لَفَشِلْتُمْ وَلَتَنَازَعْتُمْ فِي الْأَمْرِ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ سَلَّمَ ۗ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
(Ranti) nigba ti Allahu fi won han o ninu ala re (pe won) kere. Ti o ba je pe O fi won han o (pe won) po ni, eyin iba sojo, eyin iba si sariyanjiyan nipa oro naa. Sugbon Allahu ko (yin) yo. Dajudaju Oun ni Onimo nipa nnkan ti n be ninu igba-aya eda
وَإِذْ يُرِيكُمُوهُمْ إِذِ الْتَقَيْتُمْ فِي أَعْيُنِكُمْ قَلِيلًا وَيُقَلِّلُكُمْ فِي أَعْيُنِهِمْ لِيَقْضِيَ اللَّهُ أَمْرًا كَانَ مَفْعُولًا ۗ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
(Ranti) nigba ti O n fi won han yin pe won kere loju yin - nigba ti e pade (loju ogun) – O si mu eyin naa kere loju tiwon naa, nitori ki Allahu le mu oro kan ti o gbodo se wa si imuse. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

Choose other languages: