Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anbiya Ayahs #80 Translated in Yoruba

وَنُوحًا إِذْ نَادَىٰ مِنْ قَبْلُ فَاسْتَجَبْنَا لَهُ فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ مِنَ الْكَرْبِ الْعَظِيمِ
(E ranti Anabi) Nuh, nigba ti o pe ipe siwaju (yin). A si da a lohun. A si gba oun ati awon eniyan re la ninu ibanuje nla
وَنَصَرْنَاهُ مِنَ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ إِنَّهُمْ كَانُوا قَوْمَ سَوْءٍ فَأَغْرَقْنَاهُمْ أَجْمَعِينَ
A si saranse fun un lori awon eniyan t’o pe awon ayah Wa niro. Dajudaju won je ijo buruku. A si te won ri patapata
وَدَاوُودَ وَسُلَيْمَانَ إِذْ يَحْكُمَانِ فِي الْحَرْثِ إِذْ نَفَشَتْ فِيهِ غَنَمُ الْقَوْمِ وَكُنَّا لِحُكْمِهِمْ شَاهِدِينَ
(E ranti Anabi) Dawud ati (Anabi) Sulaemon, nigba ti awon mejeeji n se idajo lori (oro) oko, nigba ti agutan ijo kan jeko wo inu oko naa. Awa si je Olujerii si idajo won
فَفَهَّمْنَاهَا سُلَيْمَانَ ۚ وَكُلًّا آتَيْنَا حُكْمًا وَعِلْمًا ۚ وَسَخَّرْنَا مَعَ دَاوُودَ الْجِبَالَ يُسَبِّحْنَ وَالطَّيْرَ ۚ وَكُنَّا فَاعِلِينَ
A si fun (Anabi) Sulaemon ni agboye re. Ati pe ikookan (won) ni A fun ni ipo Anabi ati imo. A si te awon apata ati eye ba; won n se afomo (fun Allahu) pelu (Anabi) Dawud. Awa l’A se won bee
وَعَلَّمْنَاهُ صَنْعَةَ لَبُوسٍ لَكُمْ لِتُحْصِنَكُمْ مِنْ بَأْسِكُمْ ۖ فَهَلْ أَنْتُمْ شَاكِرُونَ
A tun fun un ni imo nipa sise ewu irin fun yin nitori ki o le je odi iso fun yin nibi ogun yin. Nitori naa, nje oludupe (fun Allahu) ni eyin bi

Choose other languages: