Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #34 Translated in Yoruba

وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ وُقِفُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ قَالَ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ
Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti won ba da won duro si odo Oluwa won, O si maa so pe: “Se eyi ki i se ododo bi?” Won a si wi pe: “Rara (ododo ni), Oluwa wa.” (Allahu) so pe: “Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e maa n sai gbagbo.”
قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِلِقَاءِ اللَّهِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءَتْهُمُ السَّاعَةُ بَغْتَةً قَالُوا يَا حَسْرَتَنَا عَلَىٰ مَا فَرَّطْنَا فِيهَا وَهُمْ يَحْمِلُونَ أَوْزَارَهُمْ عَلَىٰ ظُهُورِهِمْ ۚ أَلَا سَاءَ مَا يَزِرُونَ
Dajudaju awon t’o pe pipade Allahu (lorun) niro ti sofo debi pe nigba ti Akoko naa ba de ba won lojiji, won a wi pe: “A ka abamo lori ohun ti a fi jafira.” Won si maa ru ese won seyin won. Kiye si i, ohun ti won yoo ru lese si buru
وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا لَعِبٌ وَلَهْوٌ ۖ وَلَلدَّارُ الْآخِرَةُ خَيْرٌ لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ ۗ أَفَلَا تَعْقِلُونَ
Isemi aye ko si je kini kan bi ko se ere ati iranu. Ogba Ikeyin si loore julo fun awon t’o n beru (Allahu). Se e o se laakaye ni
قَدْ نَعْلَمُ إِنَّهُ لَيَحْزُنُكَ الَّذِي يَقُولُونَ ۖ فَإِنَّهُمْ لَا يُكَذِّبُونَكَ وَلَٰكِنَّ الظَّالِمِينَ بِآيَاتِ اللَّهِ يَجْحَدُونَ
A kuku ti mo pe ohun ti won n wi yoo ba o ninu je. Dajudaju won ko le pe o ni opuro, sugbon awon alabosi n tako awon ayah Allahu ni
وَلَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِكَ فَصَبَرُوا عَلَىٰ مَا كُذِّبُوا وَأُوذُوا حَتَّىٰ أَتَاهُمْ نَصْرُنَا ۚ وَلَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَاتِ اللَّهِ ۚ وَلَقَدْ جَاءَكَ مِنْ نَبَإِ الْمُرْسَلِينَ
Won kuku ti pe awon Ojise kan lopuro siwaju re. Won si se suuru lori nnkan ti won fi pe won ni opuro. Won si fi inira kan won titi di igba ti aranse Wa fi de ba won. Ko si si alayiipada kan fun awon oro Allahu. Dajudaju iro awon Ojise ti de ba o

Choose other languages: