Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #156 Translated in Yoruba

وَلَا تَقْرَبُوا مَالَ الْيَتِيمِ إِلَّا بِالَّتِي هِيَ أَحْسَنُ حَتَّىٰ يَبْلُغَ أَشُدَّهُ ۖ وَأَوْفُوا الْكَيْلَ وَالْمِيزَانَ بِالْقِسْطِ ۖ لَا نُكَلِّفُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۖ وَإِذَا قُلْتُمْ فَاعْدِلُوا وَلَوْ كَانَ ذَا قُرْبَىٰ ۖ وَبِعَهْدِ اللَّهِ أَوْفُوا ۚ ذَٰلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ
E ma se sunmo dukia omo orukan ayafi ni ona t’o dara julo titi o fi maa dagba. E won kongo ati osuwon pe daadaa. A ko labo emi kan lorun ayafi iwon agbara re. Ti e ba soro, e se deede, ibaa je ibatan. Ki e si pe adehun Allahu. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le lo iranti
وَأَنَّ هَٰذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيمًا فَاتَّبِعُوهُ ۖ وَلَا تَتَّبِعُوا السُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمْ عَنْ سَبِيلِهِ ۚ ذَٰلِكُمْ وَصَّاكُمْ بِهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ
Ati pe dajudaju eyi ni ona Mi (ti o je ona) taara. Nitori naa, e tele e. E ma se tele awon oju ona (miiran) nitori ki o ma baa mu yin yapa oju ona (esin) Re. Iyen l’O pa lase fun yin nitori ki e le beru (Re)
ثُمَّ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ تَمَامًا عَلَى الَّذِي أَحْسَنَ وَتَفْصِيلًا لِكُلِّ شَيْءٍ وَهُدًى وَرَحْمَةً لَعَلَّهُمْ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ يُؤْمِنُونَ
Leyin naa, A fun (Anabi) Musa ni Tira ni pipe perepere fun eni ti o maa se daadaa. (O je) alaye fun gbogbo nnkan. (O tun je) imona ati ike nitori ki won le ni igbagbo ninu ipade Oluwa won
وَهَٰذَا كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ مُبَارَكٌ فَاتَّبِعُوهُ وَاتَّقُوا لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
Eyi ni Tira ibukun ti A sokale. Nitori naa, e tele e. Ki e si beru (Allahu) nitori ki A le ke yin
أَنْ تَقُولُوا إِنَّمَا أُنْزِلَ الْكِتَابُ عَلَىٰ طَائِفَتَيْنِ مِنْ قَبْلِنَا وَإِنْ كُنَّا عَنْ دِرَاسَتِهِمْ لَغَافِلِينَ
Nitori ki e ma se wi pe: “Owo ijo meji ti o siwaju wa ni Won so Tira kale fun. A si je alainimo nipa eko won.”

Choose other languages: