Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #43 Translated in Yoruba

فَنَادَتْهُ الْمَلَائِكَةُ وَهُوَ قَائِمٌ يُصَلِّي فِي الْمِحْرَابِ أَنَّ اللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحْيَىٰ مُصَدِّقًا بِكَلِمَةٍ مِنَ اللَّهِ وَسَيِّدًا وَحَصُورًا وَنَبِيًّا مِنَ الصَّالِحِينَ
Nitori naa, awon molaika pe e nigba ti o n kirun lowo ninu ile ijosin, (won so pe): "Dajudaju Allahu n fun o ni iro idunnu nipa (bibi) Yahya. O maa fi ododo rinle nipa oro kan lati odo Allahu. (O maa je) asiwaju, ti ko si nii sunmo obinrin. (O maa je) Anabi. O si wa ninu awon eni rere
قَالَ رَبِّ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَامٌ وَقَدْ بَلَغَنِيَ الْكِبَرُ وَامْرَأَتِي عَاقِرٌ ۖ قَالَ كَذَٰلِكَ اللَّهُ يَفْعَلُ مَا يَشَاءُ
(Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, bawo ni emi yoo se ni omokunrin; mo ma ti dagbalagba, agan si ni obinrin mi?” (Molaika) so pe: “Bayen ni Allahu se n se ohun ti O ba fe.”
قَالَ رَبِّ اجْعَلْ لِي آيَةً ۖ قَالَ آيَتُكَ أَلَّا تُكَلِّمَ النَّاسَ ثَلَاثَةَ أَيَّامٍ إِلَّا رَمْزًا ۗ وَاذْكُرْ رَبَّكَ كَثِيرًا وَسَبِّحْ بِالْعَشِيِّ وَالْإِبْكَارِ
(Zakariyya) so pe: “Oluwa mi, fun mi ni ami kan.” (Molaika) so pe: "Ami re ni pe iwo ko nii le ba eniyan soro fun ojo meta ayafi titoka (si nnkan). Ranti Oluwa re lopolopo. Ki o si safomo (fun Un) ni asale ati ni owuro kutu
وَإِذْ قَالَتِ الْمَلَائِكَةُ يَا مَرْيَمُ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَاكِ وَطَهَّرَكِ وَاصْطَفَاكِ عَلَىٰ نِسَاءِ الْعَالَمِينَ
(E ranti) nigba ti awon molaika so pe: “Moryam, dajudaju Allahu sa o lesa. O fo o mo. O si sa o lesa lori awon obinrin aye (asiko tire)
يَا مَرْيَمُ اقْنُتِي لِرَبِّكِ وَاسْجُدِي وَارْكَعِي مَعَ الرَّاكِعِينَ
Moryam, tele ase Oluwa re. Fori kanle fun Un. Ki o si dawo te orunkun pelu awon oludawote-orunkun (lori irun)

Choose other languages: