Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #187 Translated in Yoruba

الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ عَهِدَ إِلَيْنَا أَلَّا نُؤْمِنَ لِرَسُولٍ حَتَّىٰ يَأْتِيَنَا بِقُرْبَانٍ تَأْكُلُهُ النَّارُ ۗ قُلْ قَدْ جَاءَكُمْ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِي بِالْبَيِّنَاتِ وَبِالَّذِي قُلْتُمْ فَلِمَ قَتَلْتُمُوهُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Awon t’o wi pe: "Dajudaju Allahu sadehun fun wa pe a o gbodo gba Ojise kan gbo titi o maa fi mu saraa kan wa fun wa ti ina (atorunwa) yoo fi lanu." So pe: "Dajudaju awon Ojise kan ti wa ba yin siwaju mi pelu awon eri to yanju ati eyi ti e wi (yii), nitori ki ni e fi pa won ti e ba je olododo
فَإِنْ كَذَّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِكَ جَاءُوا بِالْبَيِّنَاتِ وَالزُّبُرِ وَالْكِتَابِ الْمُنِيرِ
Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise t’o siwaju re ni opuro. Won wa pelu awon eri t’o yanju, ipin-ipin Tira ati Tira t’o n tanmole si oro esin
كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۖ فَمَنْ زُحْزِحَ عَنِ النَّارِ وَأُدْخِلَ الْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ ۗ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا مَتَاعُ الْغُرُورِ
Emi kookan lo maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enikeni ti A ba mu jinna tefe si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye bi ko se igbadun etan
لَتُبْلَوُنَّ فِي أَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ وَلَتَسْمَعُنَّ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِكُمْ وَمِنَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا أَذًى كَثِيرًا ۚ وَإِنْ تَصْبِرُوا وَتَتَّقُوا فَإِنَّ ذَٰلِكَ مِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ
Dajudaju A o maa dan yin wo ninu dukia yin ati emi yin. Dajudaju eyin yoo maa gbo opolopo oro ipalara lati odo awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon osebo. Ti eyin ba se suuru, ti e si beru (Allahu), dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan
وَإِذْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ لَتُبَيِّنُنَّهُ لِلنَّاسِ وَلَا تَكْتُمُونَهُ فَنَبَذُوهُ وَرَاءَ ظُهُورِهِمْ وَاشْتَرَوْا بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۖ فَبِئْسَ مَا يَشْتَرُونَ
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun awon ti A fun ni tira pe e gbodo se alaye re fun awon eniyan, e o si gbodo fi pamo. Won si ju u seyin leyin won. Won si ta a ni owo kekere. Nitori naa, ohun ti won n ta ma si buru (niya)

Choose other languages: