Surah Aal-E-Imran Ayahs #189 Translated in Yoruba
كُلُّ نَفْسٍ ذَائِقَةُ الْمَوْتِ ۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوْنَ أُجُورَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۖ فَمَنْ زُحْزِحَ عَنِ النَّارِ وَأُدْخِلَ الْجَنَّةَ فَقَدْ فَازَ ۗ وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا إِلَّا مَتَاعُ الْغُرُورِ
Emi kookan lo maa to iku wo. A o si san yin ni esan yin ni ekunrere ni Ojo Ajinde. Nitori naa, enikeni ti A ba mu jinna tefe si Ina, ti A si mu wo inu Ogba Idera, o kuku ti jere. Ki si ni igbesi aye bi ko se igbadun etan
لَتُبْلَوُنَّ فِي أَمْوَالِكُمْ وَأَنْفُسِكُمْ وَلَتَسْمَعُنَّ مِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ مِنْ قَبْلِكُمْ وَمِنَ الَّذِينَ أَشْرَكُوا أَذًى كَثِيرًا ۚ وَإِنْ تَصْبِرُوا وَتَتَّقُوا فَإِنَّ ذَٰلِكَ مِنْ عَزْمِ الْأُمُورِ
Dajudaju A o maa dan yin wo ninu dukia yin ati emi yin. Dajudaju eyin yoo maa gbo opolopo oro ipalara lati odo awon ti A fun ni tira siwaju yin ati awon osebo. Ti eyin ba se suuru, ti e si beru (Allahu), dajudaju iyen wa ninu awon ipinnu oro t’o pon dandan
وَإِذْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ لَتُبَيِّنُنَّهُ لِلنَّاسِ وَلَا تَكْتُمُونَهُ فَنَبَذُوهُ وَرَاءَ ظُهُورِهِمْ وَاشْتَرَوْا بِهِ ثَمَنًا قَلِيلًا ۖ فَبِئْسَ مَا يَشْتَرُونَ
(E ranti) nigba ti Allahu gba adehun awon ti A fun ni tira pe e gbodo se alaye re fun awon eniyan, e o si gbodo fi pamo. Won si ju u seyin leyin won. Won si ta a ni owo kekere. Nitori naa, ohun ti won n ta ma si buru (niya)
لَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ يَفْرَحُونَ بِمَا أَتَوْا وَيُحِبُّونَ أَنْ يُحْمَدُوا بِمَا لَمْ يَفْعَلُوا فَلَا تَحْسَبَنَّهُمْ بِمَفَازَةٍ مِنَ الْعَذَابِ ۖ وَلَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
E ma se lero pe awon t’o n dunnu si ohun ti won se (ni aidaa maa la ninu iya). Won si nifee si ki awon (eniyan) maa yin won fun ohun ti won ko se (nise rere). Nitori naa, e ma se ro won ro igbala nibi Iya. Iya eleta elero si wa fun won
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
