Quran Apps in many lanuages:

Surah Aal-E-Imran Ayahs #163 Translated in Yoruba

فَبِمَا رَحْمَةٍ مِنَ اللَّهِ لِنْتَ لَهُمْ ۖ وَلَوْ كُنْتَ فَظًّا غَلِيظَ الْقَلْبِ لَانْفَضُّوا مِنْ حَوْلِكَ ۖ فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الْأَمْرِ ۖ فَإِذَا عَزَمْتَ فَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَوَكِّلِينَ
Ike kan lati odo Allahu l’o kuku ro o fun won; ti o ba je pe o je eni buruku, olokan lile, won iba ti tuka kuro lodo re. Samoju kuro fun won, ba won toro aforijin, ki o si ba won jiroro lori oro. Ti o ba si pinnu (oro kan), ki o gbarale Allahu. Dajudaju Allahu nifee awon olugbarale E
إِنْ يَنْصُرْكُمُ اللَّهُ فَلَا غَالِبَ لَكُمْ ۖ وَإِنْ يَخْذُلْكُمْ فَمَنْ ذَا الَّذِي يَنْصُرُكُمْ مِنْ بَعْدِهِ ۗ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ
Ti Allahu ba se aranse fun yin, ko si eni ti o maa bori yin. Ti O ba si yepere yin, ta si ni eni ti o maa se aranse fun yin leyin Re? Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale
وَمَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَنْ يَغُلَّ ۚ وَمَنْ يَغْلُلْ يَأْتِ بِمَا غَلَّ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۚ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفْسٍ مَا كَسَبَتْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ
Ko letoo fun Anabi kan lati ji mu ninu oro ogun siwaju ki won to pin in. Enikeni ti o ba ji oro ogun mu siwaju ki won to pin in, o maa da ohun ti o ji mu ninu oro ogun naa pada ni Ojo Ajinde. Leyin naa, A oo san emi kookan ni esan ohun ti o se nise. A o si nii se abosi si won
أَفَمَنِ اتَّبَعَ رِضْوَانَ اللَّهِ كَمَنْ بَاءَ بِسَخَطٍ مِنَ اللَّهِ وَمَأْوَاهُ جَهَنَّمُ ۚ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Se eni ti o (sise) to iyonu Allahu da bi eni ti o pada wale pelu ibinu lati odo Allahu, ibugbe re si ni ina Jahanamo? Ikangun naa si buru
هُمْ دَرَجَاتٌ عِنْدَ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا يَعْمَلُونَ
(Ekinni keji ero inu Ogba Idera ati ero inu Ina ni) won ni ipo (otooto) ni odo Allahu. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti won n se nise

Choose other languages: