Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #82 Translated in Yoruba

قَالُوا يَا أَيُّهَا الْعَزِيزُ إِنَّ لَهُ أَبًا شَيْخًا كَبِيرًا فَخُذْ أَحَدَنَا مَكَانَهُ ۖ إِنَّا نَرَاكَ مِنَ الْمُحْسِنِينَ
Won so pe: "Iwo oba, dajudaju o ni baba arugbo agbalagba kan. Nitori naa, mu eni kan ninu wa dipo re. Dajudaju awa n ri iwo pe o wa ninu awon eni-rere
قَالَ مَعَاذَ اللَّهِ أَنْ نَأْخُذَ إِلَّا مَنْ وَجَدْنَا مَتَاعَنَا عِنْدَهُ إِنَّا إِذًا لَظَالِمُونَ
O so pe: “Mo sadi Allahu pe ki a mu eni kan afi eni ti a ba eru wa lodo re. (Ti a ba mu elomiiran) dajudaju nigba naa alabosi ni wa.”
فَلَمَّا اسْتَيْأَسُوا مِنْهُ خَلَصُوا نَجِيًّا ۖ قَالَ كَبِيرُهُمْ أَلَمْ تَعْلَمُوا أَنَّ أَبَاكُمْ قَدْ أَخَذَ عَلَيْكُمْ مَوْثِقًا مِنَ اللَّهِ وَمِنْ قَبْلُ مَا فَرَّطْتُمْ فِي يُوسُفَ ۖ فَلَنْ أَبْرَحَ الْأَرْضَ حَتَّىٰ يَأْذَنَ لِي أَبِي أَوْ يَحْكُمَ اللَّهُ لِي ۖ وَهُوَ خَيْرُ الْحَاكِمِينَ
Nigba ti won soreti nu nipa re, won te soro. Agba (ninu) won so pe: “Se e ko mo pe dajudaju baba yin ti gba adehun yin ti (e se ni oruko) Allahu. Ati pe siwaju (eyi, e ti se) aseeto nipa oro (Anabi) Yusuf. Nitori naa, emi ko nii fi ile (Misro) sile titi baba mi yoo fi yonda fun mi tabi (titi) Allahu yoo fi se idajo fun mi. O si loore julo ninu awon oludajo
ارْجِعُوا إِلَىٰ أَبِيكُمْ فَقُولُوا يَا أَبَانَا إِنَّ ابْنَكَ سَرَقَ وَمَا شَهِدْنَا إِلَّا بِمَا عَلِمْنَا وَمَا كُنَّا لِلْغَيْبِ حَافِظِينَ
E pada sodo baba yin, ki e si so pe: “Baba wa, dajudaju omo re jale. A ko si le jerii (si kini kan) afi ohun ti a ba nimo (nipa) re. Awa ko si je oluso fun ohun ti o pamo (fun wa)
وَاسْأَلِ الْقَرْيَةَ الَّتِي كُنَّا فِيهَا وَالْعِيرَ الَّتِي أَقْبَلْنَا فِيهَا ۖ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
Ki o si bi awon ara ilu ti a wa ninu re ati ero-rakunmi ti a jo dari de leere wo. Dajudaju olododo ma ni wa.”

Choose other languages: