Quran Apps in many lanuages:

Surah Yunus Ayahs #74 Translated in Yoruba

مَتَاعٌ فِي الدُّنْيَا ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ الْعَذَابَ الشَّدِيدَ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ
Igbadun bin-intin (le wa fun won) nile aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi won. Leyin naa, A oo fun won ni iya lile to wo nitori pe won n sai gbagbo
وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ نُوحٍ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ إِنْ كَانَ كَبُرَ عَلَيْكُمْ مَقَامِي وَتَذْكِيرِي بِآيَاتِ اللَّهِ فَعَلَى اللَّهِ تَوَكَّلْتُ فَأَجْمِعُوا أَمْرَكُمْ وَشُرَكَاءَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُنْ أَمْرُكُمْ عَلَيْكُمْ غُمَّةً ثُمَّ اقْضُوا إِلَيَّ وَلَا تُنْظِرُونِ
Ka iroyin (Anabi) Nuh fun won. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Eyin eniyan mi, ti o ba je pe iduro mi (pelu yin) ati bi mo se n fi awon ayah Allahu se isiti fun yin ba lagbara lara yin, nigba naa Allahu ni mo gbarale. Nitori naa, e pa imoran yin po, (ki e si ke pe) awon orisa yin. Leyin naa, ki ipinnu oro yin ma se wa ni bonkele laaarin yin. Leyin naa, ki e yanju oro mi. Ki e si ma se lo mi lara mo
فَإِنْ تَوَلَّيْتُمْ فَمَا سَأَلْتُكُمْ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللَّهِ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْمُسْلِمِينَ
Ti e ba si koyin (si iranti), emi ko kuku toro owo-oya kan lowo yin. Ko si esan kan fun mi (nibi kan) bi ko se lodo Allahu. Won si ti pa mi lase pe ki ng wa ninu awon musulumi.”
فَكَذَّبُوهُ فَنَجَّيْنَاهُ وَمَنْ مَعَهُ فِي الْفُلْكِ وَجَعَلْنَاهُمْ خَلَائِفَ وَأَغْرَقْنَا الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۖ فَانْظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنْذَرِينَ
Nigba naa, won pe e ni opuro. Nitori naa, A gba a la, oun ati awon t’o n be pelu re ninu oko oju-omi. A si se won ni arole (lori ile). A si te awon t’o pe ayah Wa niro ri sinu agbami. Nitori naa, wo bi ikangun awon eni-akilo-fun se ri
ثُمَّ بَعَثْنَا مِنْ بَعْدِهِ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا بِمَا كَذَّبُوا بِهِ مِنْ قَبْلُ ۚ كَذَٰلِكَ نَطْبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِ الْمُعْتَدِينَ
Leyin naa, A gbe awon Ojise kan dide si awon ijo won. Won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon naa ko kuku gbagbo ninu ohun ti (ijo Anabi Nuh) pe niro siwaju (won, iyen ni pe, iru kan-un ni won). Bayen ni A se n fi edidi bo okan awon alakoyo

Choose other languages: