Quran Apps in many lanuages:

Surah Ta-Ha Ayahs #117 Translated in Yoruba

وَكَذَٰلِكَ أَنْزَلْنَاهُ قُرْآنًا عَرَبِيًّا وَصَرَّفْنَا فِيهِ مِنَ الْوَعِيدِ لَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ أَوْ يُحْدِثُ لَهُمْ ذِكْرًا
Bayen ni A se so (iranti) kale ni ohun kike pelu ede Larubawa. A si se alaye oniran-anran ileri sinu re nitori ki won le sora (fun iya) tabi nitori ki o le je iranti fun won
فَتَعَالَى اللَّهُ الْمَلِكُ الْحَقُّ ۗ وَلَا تَعْجَلْ بِالْقُرْآنِ مِنْ قَبْلِ أَنْ يُقْضَىٰ إِلَيْكَ وَحْيُهُ ۖ وَقُلْ رَبِّ زِدْنِي عِلْمًا
Nitori naa, Allahu Oba Ododo ga julo. Ma se kanju pelu al-Ƙur’an siwaju ki won to pari imisi re fun o. Ki o si so pe: “Oluwa mi, salekun imo fun mi.”
وَلَقَدْ عَهِدْنَا إِلَىٰ آدَمَ مِنْ قَبْلُ فَنَسِيَ وَلَمْ نَجِدْ لَهُ عَزْمًا
Dajudaju A se adehun fun (Anabi) Adam siwaju. Sugbon o gbagbe. A ko si ba a pelu ipinnu okan
وَإِذْ قُلْنَا لِلْمَلَائِكَةِ اسْجُدُوا لِآدَمَ فَسَجَدُوا إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ
Nigba ti A so fun awon molaika pe: “E fori kanle ki Adam. Won si fori kanle ki i afi ’Iblis, (ti) o ko.”
فَقُلْنَا يَا آدَمُ إِنَّ هَٰذَا عَدُوٌّ لَكَ وَلِزَوْجِكَ فَلَا يُخْرِجَنَّكُمَا مِنَ الْجَنَّةِ فَتَشْقَىٰ
Nitori naa, A so pe: "Adam, dajudaju eyi ni ota fun iwo ati iyawo re. Nitori naa, ko gbodo mu eyin mejeeji jade kuro ninu Ogba Idera nitori ki o ma baa daamu (fun ije-imu)

Choose other languages: