Quran Apps in many lanuages:

Surah Muhammad Ayahs #16 Translated in Yoruba

إِنَّ اللَّهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَهُمْ
Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon t’o si sai gbagbo, awon n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran-osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won
وَكَأَيِّنْ مِنْ قَرْيَةٍ هِيَ أَشَدُّ قُوَّةً مِنْ قَرْيَتِكَ الَّتِي أَخْرَجَتْكَ أَهْلَكْنَاهُمْ فَلَا نَاصِرَ لَهُمْ
Meloo meloo ninu awon (ara) ilu ti o lagbara ju (ara) ilu re, ti o le o jade, ti A si ti pa won re. Ko si si alaranse kan fun won
أَفَمَنْ كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّهِ كَمَنْ زُيِّنَ لَهُ سُوءُ عَمَلِهِ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ
Nje eni ti o wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re, se o da bi eni ti won se ise aburu re ni oso fun, ti won si tele ife-inu won
مَثَلُ الْجَنَّةِ الَّتِي وُعِدَ الْمُتَّقُونَ ۖ فِيهَا أَنْهَارٌ مِنْ مَاءٍ غَيْرِ آسِنٍ وَأَنْهَارٌ مِنْ لَبَنٍ لَمْ يَتَغَيَّرْ طَعْمُهُ وَأَنْهَارٌ مِنْ خَمْرٍ لَذَّةٍ لِلشَّارِبِينَ وَأَنْهَارٌ مِنْ عَسَلٍ مُصَفًّى ۖ وَلَهُمْ فِيهَا مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ وَمَغْفِرَةٌ مِنْ رَبِّهِمْ ۖ كَمَنْ هُوَ خَالِدٌ فِي النَّارِ وَسُقُوا مَاءً حَمِيمًا فَقَطَّعَ أَمْعَاءَهُمْ
Apejuwe Ogba Idera eyi ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (niyi): awon omi odo wa ninu re ti ko nii yi pada ati awon odo wara ti adun re ko nii yi pada ati awon odo oti didun fun awon t’o maa mu un ati awon odo oyin mimo. Awon oniruuru eso wa fun won ninu re ati aforijin lati odo Oluwa won. (Se eni ti o wa ninu Ogba Idera yii) da bi olusegbere ninu Ina bi, ti won n fun won ni omi gbigbona mu, ti o si maa ja awon ifun won putuputu
وَمِنْهُمْ مَنْ يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ حَتَّىٰ إِذَا خَرَجُوا مِنْ عِنْدِكَ قَالُوا لِلَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مَاذَا قَالَ آنِفًا ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ طَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ
O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won

Choose other languages: