Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #10 Translated in Yoruba

وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ أَنْجَاكُمْ مِنْ آلِ فِرْعَوْنَ يَسُومُونَكُمْ سُوءَ الْعَذَابِ وَيُذَبِّحُونَ أَبْنَاءَكُمْ وَيَسْتَحْيُونَ نِسَاءَكُمْ ۚ وَفِي ذَٰلِكُمْ بَلَاءٌ مِنْ رَبِّكُمْ عَظِيمٌ
(Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe e ranti ike Allahu lori yin nigba ti O gba yin la lowo awon eniyan Fir‘aon, ti won n fi iya buruku je yin; won n dunnbu awon omokunrin yin, won si n da awon omobinrin yin si. Adanwo nla wa ninu iyen lati odo Oluwa yin
وَإِذْ تَأَذَّنَ رَبُّكُمْ لَئِنْ شَكَرْتُمْ لَأَزِيدَنَّكُمْ ۖ وَلَئِنْ كَفَرْتُمْ إِنَّ عَذَابِي لَشَدِيدٌ
(E ranti) nigba ti Oluwa Eledaa yin so o di mimo (fun yin pe): "Dajudaju ti e ba dupe, Emi yoo salekun fun yin. Dajudaju ti e ba si saimoore, dajudaju iya Mi ma le
وَقَالَ مُوسَىٰ إِنْ تَكْفُرُوا أَنْتُمْ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا فَإِنَّ اللَّهَ لَغَنِيٌّ حَمِيدٌ
(Anabi) Musa so pe: "Ti e ba saimoore, eyin ati awon t’o n be lori ile aye patapata, dajudaju Allahu ni Oloro, Olope
أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَبَأُ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِكُمْ قَوْمِ نُوحٍ وَعَادٍ وَثَمُودَ ۛ وَالَّذِينَ مِنْ بَعْدِهِمْ ۛ لَا يَعْلَمُهُمْ إِلَّا اللَّهُ ۚ جَاءَتْهُمْ رُسُلُهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَرَدُّوا أَيْدِيَهُمْ فِي أَفْوَاهِهِمْ وَقَالُوا إِنَّا كَفَرْنَا بِمَا أُرْسِلْتُمْ بِهِ وَإِنَّا لَفِي شَكٍّ مِمَّا تَدْعُونَنَا إِلَيْهِ مُرِيبٍ
Se iro awon t’o siwaju yin ko ti i de ba yin ni? Ijo (Anabi) Nuh, ijo ‘Ad, ijo Thamud ati awon t’o wa leyin won; ko si eni ti o mo won afi Allahu. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nigba naa, won ti owo won bo enu won (ni ti ibinu), won si wi pe: "Dajudaju awa sai gbagbo ninu nnkan ti Won fi ran yin nise. Ati pe dajudaju awa wa ninu iyemeji t’o gbopon nipa ohun ti e n pe wa si
قَالَتْ رُسُلُهُمْ أَفِي اللَّهِ شَكٌّ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ يَدْعُوكُمْ لِيَغْفِرَ لَكُمْ مِنْ ذُنُوبِكُمْ وَيُؤَخِّرَكُمْ إِلَىٰ أَجَلٍ مُسَمًّى ۚ قَالُوا إِنْ أَنْتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِثْلُنَا تُرِيدُونَ أَنْ تَصُدُّونَا عَمَّا كَانَ يَعْبُدُ آبَاؤُنَا فَأْتُونَا بِسُلْطَانٍ مُبِينٍ
Awon Ojise won so pe: “Se iyemeji kan n be nibi (bibe) Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile? O n pe yin nitori ki O le fori awon ese yin jin yin ati nitori ki O le lo yin lara di gbedeke akoko kan.” Won wi pe: “Eyin ko je kini kan tayo abara bi iru wa. Eyin si fe se wa lori kuro nibi nnkan ti awon baba wa n josin fun. Nitori naa, e fun wa ni eri ponnbele.”

Choose other languages: