Quran Apps in many lanuages:

Surah Ibrahim Ayahs #37 Translated in Yoruba

وَسَخَّرَ لَكُمُ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ دَائِبَيْنِ ۖ وَسَخَّرَ لَكُمُ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ
O ro oorun ati osupa fun yin, ti mejeeji n rin lai sinmi. O tun ro oru ati osan fun yin
وَآتَاكُمْ مِنْ كُلِّ مَا سَأَلْتُمُوهُ ۚ وَإِنْ تَعُدُّوا نِعْمَتَ اللَّهِ لَا تُحْصُوهَا ۗ إِنَّ الْإِنْسَانَ لَظَلُومٌ كَفَّارٌ
Ati pe O n fun yin ninu gbogbo nnkan ti e toro lodo Re. Ti e ba se onka idera Allahu, e ko le ka a tan. Dajudaju eniyan ni alabosi alaimoore
وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ اجْعَلْ هَٰذَا الْبَلَدَ آمِنًا وَاجْنُبْنِي وَبَنِيَّ أَنْ نَعْبُدَ الْأَصْنَامَ
(Ranti) nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, se ilu yii ni ilu ifayabale. Ki O si mu emi ati awon omo mi jinna si jijosin fun awon orisa
رَبِّ إِنَّهُنَّ أَضْلَلْنَ كَثِيرًا مِنَ النَّاسِ ۖ فَمَنْ تَبِعَنِي فَإِنَّهُ مِنِّي ۖ وَمَنْ عَصَانِي فَإِنَّكَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Oluwa mi, dajudaju awon orisa ti ko opolopo ninu awon eniyan sonu. Nitori naa, enikeni ti o ba tele mi, dajudaju oun ni eni mi. Enikeni ti o ba si yapa mi, dajudaju Iwo ni Alaforijin, Asake
رَبَّنَا إِنِّي أَسْكَنْتُ مِنْ ذُرِّيَّتِي بِوَادٍ غَيْرِ ذِي زَرْعٍ عِنْدَ بَيْتِكَ الْمُحَرَّمِ رَبَّنَا لِيُقِيمُوا الصَّلَاةَ فَاجْعَلْ أَفْئِدَةً مِنَ النَّاسِ تَهْوِي إِلَيْهِمْ وَارْزُقْهُمْ مِنَ الثَّمَرَاتِ لَعَلَّهُمْ يَشْكُرُونَ
Oluwa wa, dajudaju emi wa ibugbe fun aromodomo mi si ile afonifoji, ile ti ko ni eso, nitosi Ile Re Olowo. Oluwa wa, nitori ki won le kirun ni. Nitori naa, je ki okan awon eniyan fa sodo won. Ki O si pese awon eso fun won nitori ki won le dupe (fun O)

Choose other languages: