Quran Apps in many lanuages:

Surah Fussilat Ayahs #54 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ رَحْمَةً مِنَّا مِنْ بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَا أَظُنُّ السَّاعَةَ قَائِمَةً وَلَئِنْ رُجِعْتُ إِلَىٰ رَبِّي إِنَّ لِي عِنْدَهُ لَلْحُسْنَىٰ ۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا بِمَا عَمِلُوا وَلَنُذِيقَنَّهُمْ مِنْ عَذَابٍ غَلِيظٍ
Dajudaju ti A ba se idera fun un lati odo Wa leyin aburu ti o fowo ba a, dajudaju o maa wi pe: "Eyi ni temi. Emi ko si ni amodaju pe Akoko naa maa sele. Ati pe dajudaju ti Won ba da mi pada si odo Oluwa mi, dajudaju rere tun wa fun mi ni odo Re." Dajudaju Awa yoo fun awon t’o sai gbagbo ni iro ohun ti won se nise. Dajudaju A si maa fun won ni iya t’o nipon to wo
وَإِذَا أَنْعَمْنَا عَلَى الْإِنْسَانِ أَعْرَضَ وَنَأَىٰ بِجَانِبِهِ وَإِذَا مَسَّهُ الشَّرُّ فَذُو دُعَاءٍ عَرِيضٍ
Ati pe nigba ti A ba se idera fun eniyan, o maa gbunri (kuro ni odo Wa). O si maa segberaga. Nigba ti aburu ba si fowo ba a, nigba naa l’o maa di aladuaa regede
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كَانَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ ثُمَّ كَفَرْتُمْ بِهِ مَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ هُوَ فِي شِقَاقٍ بَعِيدٍ
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe al-Ƙur’an wa lati odo Allahu, leyin naa ti e sai gbagbo ninu re (se eyin ko ti wa ninu iyapa bi?)" Ta l’o sina ju eni ti o wa ninu iyapa t’o jinna (si ododo)
سَنُرِيهِمْ آيَاتِنَا فِي الْآفَاقِ وَفِي أَنْفُسِهِمْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمْ أَنَّهُ الْحَقُّ ۗ أَوَلَمْ يَكْفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ
A oo maa fi awon ami Wa han won ninu ofurufu ati ninu emi ara won titi o maa fi han kedere si won pe dajudaju al-Ƙur’an ni ododo. Nje Oluwa re ko to ki o je pe dajudaju Oun ni Arinu-rode lori gbogbo nnkan
أَلَا إِنَّهُمْ فِي مِرْيَةٍ مِنْ لِقَاءِ رَبِّهِمْ ۗ أَلَا إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُحِيطٌ
Gbo, dajudaju won wa ninu iyemeji nipa ipade Oluwa won. Gbo, dajudaju Allahu yi gbogbo nnkan ka

Choose other languages: