Quran Apps in many lanuages:

Surah Az-Zamar Ayahs #6 Translated in Yoruba

إِنَّا أَنْزَلْنَا إِلَيْكَ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ فَاعْبُدِ اللَّهَ مُخْلِصًا لَهُ الدِّينَ
Dajudaju Awa so Tira (al-Ƙur’an) kale fun o pelu ododo. Nitori naa, josin fun Allahu ni olusafomo-esin fun Un
أَلَا لِلَّهِ الدِّينُ الْخَالِصُ ۚ وَالَّذِينَ اتَّخَذُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ مَا نَعْبُدُهُمْ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَا إِلَى اللَّهِ زُلْفَىٰ إِنَّ اللَّهَ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ فِي مَا هُمْ فِيهِ يَخْتَلِفُونَ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي مَنْ هُوَ كَاذِبٌ كَفَّارٌ
Gbo! Ti Allahu ni esin mimo. Awon ti won si mu awon alafeyinti kan yato si Allahu, (won wi pe): "A o josin fun won bi ko se pe nitori ki won le mu wa sunmo Allahu pekipeki ni." Dajudaju Allahu l’O maa dajo laaarin won nipa ohun ti won n yapa enu nipa re (iyen, esin ’Islam). Dajudaju Allahu ki i fi ona mo eni ti o je opuro, alaigbagbo
لَوْ أَرَادَ اللَّهُ أَنْ يَتَّخِذَ وَلَدًا لَاصْطَفَىٰ مِمَّا يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ سُبْحَانَهُ ۖ هُوَ اللَّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
Ti o ba je pe Allahu ba fe fi eni kan se omo ni, iba sesa ohun ti O ba fe (fi somo) ninu nnkan ti O da. Mimo ni fun Un (nibi eyi). Oun ni Allahu, Okan soso, Olubori
خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِالْحَقِّ ۖ يُكَوِّرُ اللَّيْلَ عَلَى النَّهَارِ وَيُكَوِّرُ النَّهَارَ عَلَى اللَّيْلِ ۖ وَسَخَّرَ الشَّمْسَ وَالْقَمَرَ ۖ كُلٌّ يَجْرِي لِأَجَلٍ مُسَمًّى ۗ أَلَا هُوَ الْعَزِيزُ الْغَفَّارُ
O seda awon sanmo ati ile pelu ododo. O n ti oru bonu osan. O si n ti osan bonu oru. O si ro oorun ati osupa; ikookan won n rin fun gbedeke akoko kan. Gbo! Oun ni Alagbara, Alaforijin
خَلَقَكُمْ مِنْ نَفْسٍ وَاحِدَةٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْهَا زَوْجَهَا وَأَنْزَلَ لَكُمْ مِنَ الْأَنْعَامِ ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ ۚ يَخْلُقُكُمْ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ خَلْقًا مِنْ بَعْدِ خَلْقٍ فِي ظُلُمَاتٍ ثَلَاثٍ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ لَهُ الْمُلْكُ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ
O seda yin lati ara emi eyo kan. Leyin naa, O da iyawo re lati ara re. O si so mejo kale fun yin ninu eran-osin ni tako-tabo. O n seda yin sinu iya yin, eda kan leyin eda kan ninu awon okunkun meta. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. TiRe ni ijoba. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo

Choose other languages: