Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Tawba Ayahs #48 Translated in Yoruba

لَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ أَنْ يُجَاهِدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالْمُتَّقِينَ
Awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin ko nii toro iyonda lodo re lati ma fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Allahu si ni Onimo nipa awon oluberu (Re)
إِنَّمَا يَسْتَأْذِنُكَ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَارْتَابَتْ قُلُوبُهُمْ فَهُمْ فِي رَيْبِهِمْ يَتَرَدَّدُونَ
Awon t’o n toro iyonda lodo re (lati jokoo sile, dipo lilo si oju-ogun) ni awon ti ko gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin; okan won si n seyemeji. Nitori naa, won n daamu kiri nibi iseye-meji won
وَلَوْ أَرَادُوا الْخُرُوجَ لَأَعَدُّوا لَهُ عُدَّةً وَلَٰكِنْ كَرِهَ اللَّهُ انْبِعَاثَهُمْ فَثَبَّطَهُمْ وَقِيلَ اقْعُدُوا مَعَ الْقَاعِدِينَ
Ti o ba je pe won gbero ijade fun ogun esin ni, won iba se ipalemo fun un. Sugbon Allahu korira idide won fun ogun esin, O si ko ifaseyin ba won. Won si so fun won pe: "E jokoo pelu awon olujokoo sile
لَوْ خَرَجُوا فِيكُمْ مَا زَادُوكُمْ إِلَّا خَبَالًا وَلَأَوْضَعُوا خِلَالَكُمْ يَبْغُونَكُمُ الْفِتْنَةَ وَفِيكُمْ سَمَّاعُونَ لَهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ
Ti o ba je pe won jade pelu yin, won ko nii kun yin afi pelu ibaje. Won yo si sare maa da rukerudo sile laaarin yin, ti won yoo maa ko yin sinu iyonu. Ati pe won ni olugboro fun won laaarin yin. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi
لَقَدِ ابْتَغَوُا الْفِتْنَةَ مِنْ قَبْلُ وَقَلَّبُوا لَكَ الْأُمُورَ حَتَّىٰ جَاءَ الْحَقُّ وَظَهَرَ أَمْرُ اللَّهِ وَهُمْ كَارِهُونَ
Won kuku ti da iyonu sile teletele. Won si doju awon oro ru fun o titi ododo fi de, ti ase Allahu si foju han kedere; emi won si ko o

Choose other languages: