Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Najm Ayahs #32 Translated in Yoruba

وَمَا لَهُمْ بِهِ مِنْ عِلْمٍ ۖ إِنْ يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ ۖ وَإِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا
Ko si imo kan fun won nipa re. Won ko si tele kini kan bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si nii roro kini kan lara ododo
فَأَعْرِضْ عَنْ مَنْ تَوَلَّىٰ عَنْ ذِكْرِنَا وَلَمْ يُرِدْ إِلَّا الْحَيَاةَ الدُّنْيَا
Nitori naa, seri kuro ni odo eni t’o keyin si iranti Wa, ti ko si gbero kini kan afi isemi aye
ذَٰلِكَ مَبْلَغُهُمْ مِنَ الْعِلْمِ ۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنْ ضَلَّ عَنْ سَبِيلِهِ وَهُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اهْتَدَىٰ
Iyen ni odiwon (ati opin) imo won. Dajudaju Oluwa re, O nimo julo nipa eni t’o sina kuro loju ona Re. O si nimo julo nipa eni t’o mona
وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ أَسَاءُوا بِمَا عَمِلُوا وَيَجْزِيَ الَّذِينَ أَحْسَنُوا بِالْحُسْنَى
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile nitori ki O le san awon t’o se ise aburu ni esan ohun ti won se nise ati nitori ki O le san awon t’o se ise rere ni esan rere
الَّذِينَ يَجْتَنِبُونَ كَبَائِرَ الْإِثْمِ وَالْفَوَاحِشَ إِلَّا اللَّمَمَ ۚ إِنَّ رَبَّكَ وَاسِعُ الْمَغْفِرَةِ ۚ هُوَ أَعْلَمُ بِكُمْ إِذْ أَنْشَأَكُمْ مِنَ الْأَرْضِ وَإِذْ أَنْتُمْ أَجِنَّةٌ فِي بُطُونِ أُمَّهَاتِكُمْ ۖ فَلَا تُزَكُّوا أَنْفُسَكُمْ ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَنِ اتَّقَىٰ
Awon t’o n jinna si ese nla nla ati iwa ibaje ayafi awon ese peepeepe, dajudaju Oluwa re gbooro ni aforijin. O nimo julo nipa yin nigba ti O seda yin lati inu ile ati nigba ti e wa ni ole ninu awon ikun iya yin. Nitori naa, e ma se fora yin mo. O nimo julo nipa eni t’o beru (Re)

Choose other languages: